Faith Adebọla, Eko
Ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Afẹnifẹre, ti sọ gbangba gbangba pe bii igba teeyan n fi asẹ gbe’jo loun ri gbogbo kukufẹfẹ tawọn oloṣelu kan n ṣe lasiko yii si, ti wọn lawọn n mura silẹ de eto idibo gbogbogboo lọdun 2023, tori o da oun loju pe lai jẹ pe wọn ba yi iwe ofin ilẹ wa ti ọdun 1999 ta a n lo lọwọ yii pada, ko le si eto idibo kankan lọdun 2023.
Olori ẹgbẹ naa, Oloye Ayọ Adebanjọ, lo sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lori eto tẹlifiṣan ori atẹ ayelujara kan ti ileeṣẹ Arise TV ṣe fun un.
Adebanjọ bẹnu atẹ lu iwe ofin orileede wa ta a n lo lọwọ yii, o ni iwe ofin to ṣegbe sẹyin ẹya kan, to si koyan ẹya mi-in kere ni, eyi lo ni o fa a ti ariwo iyapa, konko-jabele, ati ipinya fi pọ lasiko yii. O ni ariwo naa ko le rọlẹ rara, afi ti ayipada ba de ba iwe ofin naa.
O ni a gbọdọ ranti pe awọn ijọba ologun ni wọn kọ iwe ofin yii, ohun ti wọn si kọ ti yatọ patapata si erongba awọn baba nla wa ti wọn ja fun ominira Naijiria lọjọun. ‘‘Ayafi ti wọn ba paarọ iwe ofin naa, ti wọn yi i pada si bo ṣe yẹ, ko le si ilọsiwaju kan ninu ọrọ orileede yii.
“Jibiti gidi ni iwe ofin ilẹ wa ta a gbe dani yii. O ti yatọ patapata si iwe ofin tọdun 1960 tawọn to ja fun ominira orileede yii fọwọ si, iwe ofin to faaye silẹ fun ipinlẹ kọọkan ati agbegbe kọọkan lati maa ṣakoso awọn nnkan alumọọni rẹ, to si yọnda fun ọlọpaa ipinlẹ ati ti apapọ, gbogbo nnkan tawọn eeyan n ja fun bayii niwe ofin tọdun 1960 yẹn ṣalaye rẹ bo ṣe yẹ.
“A o ni i dibo, ko si le si eto idibo kan to maa waye lorileede yii, niwọn igba to ba ṣi jẹ ẹya kan lo maa maa pinnu ibi ti Aarẹ yoo ti wa fun wa. Idi niyẹn tawa o fi nigbagbọ ninu ọrọ eto idibo ọdun 2023, ayafi ti wọn ba wọgi le iwe ofin ọdun 1999 yii, ti wọn si ṣeto tuntun to maa rọpo ẹ, nibi ti eto iṣakoso yoo ti ri bo ṣe yẹ ko ri. Awa o nifẹẹ si ọrọ idibo kan rara, tori niṣe ni wọn n fi kinni naa ru wa loju, ọrọ ibo ki i jẹ ka raaye yọ igi wọrọkọ to n da ina itẹsiwaju orileede yii ru, ẹ jẹ ka pa ọrọ eto idibo ti sapa kan na, ka bojuto iwe ofin to daagun yii, aijẹ bẹẹ, bii igba ti a n yin agbado sẹyin igba ni akitiyan tawọn kan n ṣe lori ọrọ idibo 2023 maa ja si.”
Bẹẹ l’Oloye Ayọ Adebanjọ sọ.