Ko pẹ ti Ibiyẹmi tẹwọn de to tun ba wọn lọ soko ole mi-in n’Ilaro

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ti ba awọn afurasi ọdaran mẹta kan, Ibiyẹmi Wasiri, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti wọn n pe ni Fellow, Alabi Ojugbele, ẹni ogun ọdun pere, ati ẹni kẹta, Lekan Obe, ẹni ọdun mejidinlogun. Adugbo Orita, niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun, lọwọ ti ba wọn lasiko ti wọn fẹẹ lọ digunjale.
Ọkada Bajaj kan lawọn mẹtẹẹta gun laaarọ ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa yii, kaluku wọn lo gbe apo kọpa, ṣugbọn bi wọn ṣe gun ọkada naa mu ifura dani.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ni ojiji lawọn afurasi naa pade awọn agbofinro ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ilaro ti wọn n ṣe patiroolu jẹẹjẹ wọn, bi wọn ṣe yọ si wọn ni wọn bẹ danu lori ọkada, ti wọn si gba ọna ọtọọtọ lọ.
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa naa gba fi ya wọn, wọn si le wọn ba. Wọn ka ibọn oyinbo kan mọ wọn lọwọ, katiriiji ọta ibọn ti wọn ko ti i yin mẹta ati oriṣiiriṣii oogun abẹnugọngọ ni wọn tun ba lara wọn.
Ni teṣan, Ibiyẹmi Wasiri jẹwọ pe aipẹ yii loun ṣẹṣẹ ti ẹwọn de, o ni ole jija lo sọ oun dero ẹwọn, igba ti wọn tu oun silẹ loun ṣalabaapade awọn ẹmẹwa oun yii, lawọn ba jọ bẹrẹ iṣẹ adigunjale lakọtun. O tun sọ pe oun ṣi n jẹjọ lori ẹsun nini nnkan ija oloro lọwọ lai gbaṣẹ nile-ẹjọ Majisreeti kan, nipinlẹ Ogun.
Wọn lọkunrin afurasi ọdaran yii sọ fawọn ọlọpaa pe oko ole lawọn n lọ lọjọ tọwọ palaba wọn ṣegi yii.
CP Lanre Bankọle, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn mẹtẹẹta si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to n gbogun ti iwa idigunjale lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ibẹ lawọn mẹtẹẹta ti n gbatẹgun lọwọ ba a ṣe n sọ yii.
Ti iwadii ba pari, gẹgẹ bi wọn ṣe wi, gbogbo wọn maa foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply