Florence Babaṣọla
Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ti fọwọ mejeeji sọya pe ko si ẹnikẹni ti agbara rẹ, tabi iṣẹ rẹ gbe e, lati gba aaye oun tabi fọwọ rọ oun sẹyin ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun.
Arẹgbẹṣọla, ẹni to jẹ Minisita fọrọ Abẹle lorileede wa bayii ṣalaye pe lọdun mẹtadinlogun sẹyin loun jade sita nipinlẹ Ọṣun labẹ asia Ọranmiyan, ti oun pẹlu awọn eeyan kan si ba awọn iranṣẹ okunkun ati ifasẹyin jagun titi ti awọn fi fidi ẹgbẹ APC mulẹ.
Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin fun Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla, Ṣọla Faṣure, fi sita lori ohun to ṣẹlẹ lasiko to lọ fun iforukọsilẹ tẹgbẹ APC n ṣe lọwọlọwọ ni wọọdu idibo rẹ niluu Ileṣa lo ti ni, ipa manigbagbe loun ko lati fidi ẹgbẹ naa mulẹ l’Ọṣun.
O ni laalaa igba naa lo fun ẹgbẹ lanfaani lati ṣejọba lẹẹmeji leralera l’Ọṣun, to si tun ti ṣaseyọri ninu idibo aarẹ ati ti awọn aṣofin lẹẹmẹta ọtọọtọ.
O ni yoo waa nira fun awọn ti wọn ko ni iru akitiyan ati itara ti oun ni lati sọ pe ibo loun fẹẹ gbe e gba ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun.
Nipa ti awọn adari ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati ẹgbẹ mi-in ti wọn n ya wọnu ẹgbẹ APC bayii, o ni ara amuyẹ ijọba tiwa-n-tiwa ni fun awọn ti orukọ wọn ti bajẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ ti wọn ba ri i pe o ni afojusun rere, ṣugbọn ojuṣe awọn ọmọ ẹgbẹ ni lati ri i pe wọn ko fun wọn lanfaani lati de ipo aṣiwaju ki wọn ma baa ba ẹgbẹ APC jẹ.
Arẹgbẹṣọla fi kun ọrọ rẹ pe eto oṣelu abẹnu ṣe pataki ninu ijọba tiwa-n-tiwa, o rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati ṣọra fun awọn ti wọn fẹẹ fi ori orórì (grave) Oloye Bọla Ige ṣe atẹgun, ti wọn si fẹẹ ba orukọ rere ti oloogbe naa ni ninu oṣelu jẹ.
Bakan naa lo sọ fun awọn eeyan pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko sinmi rara lori ipinnu rẹ lati yanju wahala eto aabo to n dojukọ orileede yii, o ni laipẹ ni gbogbo rẹ yoo di afisẹyin teegun n fiṣọ.