Adewale Adeoye
Minisita olu ilu ilẹ wa niluu Abuja, Nyesom Wike, ti sọ pe ko seni naa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP toun jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ nibẹ bayii to le yọ oun kuro lẹgbẹ tabi kede pe wọn maa fiya kankan jẹ oun.
O sọrọ naa di mimọ lori eto pataki kan ti wọn pe e si lori tẹlifiṣan ‘Channels TV’ l’Ọjọruu, Wesidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii. O ni loootọ ẹgbẹ alatako APC lo foun nisẹ toun n ṣe lọwọ bayii, sibẹ, ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣi loun lọjọkọjọ.
‘Ẹ wo o, ẹ jẹ ka ko ila kuro lẹkọ, gbogbo ẹnu ni mo fi n sọrọ naa sita, ko sẹni ti wọn bi daa ninu awọn oloye ẹgbẹ PDP to maa loun yọ mi lẹgbẹ tabi kede pe ijiya bayii lo tọ si mi. Emi gan-an ni ma a sọ pe ki wọn fiya jẹ ọmọ ẹgbẹ yoowu to ba ṣẹ tabi tapa sofin ati ilana ẹgbe wa ti i ṣe ẹgbẹ PDP.
‘Mo n sọ o nita gbangba ni pe ba a ba ri ẹni to da loju, ko bọ sita lati waa ta ko ọrọ mi yii, ko sẹni ti wọn bi daa lati sọ pe awọn maa yọ mi lẹgbẹ tabi fiya kankan jẹ mi’.