Ko sẹni to le paṣẹ funjọba to n bọ pe bayii ni ko ṣẹ ṣe lori owo iranwo epo-Keyamo

Adewale Adeoye

Ẹka to ri seto ipolongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo aarẹ to waye loṣu Keji, ọdun yii, ti sọ pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu nikan lo le sọ igba ati akoko ti ijọba rẹ yoo fopin si owo iranwọ lori epo bẹntiroolu (Fuel Subsidy), ti ijọba apapọ n gbero lati yọ.

Ninu ọrọ ti Festus Keyamo sọ nipa ọrọ yiyọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu yii, o sọ pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu yoo fopin sọrọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa gẹgẹ bii erongba ijọba Buhari, ṣugbọn ki i ṣe gbogbo eto ijọba kan lo maa wu ẹlomiiran.

Lori bawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe n halẹ pe awọn ko ni i gba fun ijọba tuntun to n bọ lọna yii bo ba le yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu yii, Keyamo ni ọrọ ko tọ si wọn lẹnu rara, nitori pe ondije dupo aarẹ ilẹ yii lorukọ ẹgbẹ wọn, Ọgbẹni Peter Obi, paapaa fara mọ aba lati yọ owo iranwọ lori epo lakooko to n ṣepolongo ibo rẹ.

O ni Tinubu funra rẹ ni yoo sọ igba ti opin yoo de ba iranwọ ori owo epo ọhun. Keyamo ni ko sẹni to le kan an nipa funjọba to n bọ pe bakan ni ko ṣe ṣe ijọba rẹ.

Ijọba Aarẹ Buhari ti sọ pe o ṣee ṣe ki ijọba oun fopin si ọrọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa ko too di pe oun gbe ijọba silẹ ninu oṣu Karun-un, ọdun yii, o ni owo iranwọ lori epo tijọba oun ṣe afikun rẹ sinu eto iṣuna yii yoo dopin ninu oṣu Kẹfa, ko si daju rara pe ijọba tuntun to n bọ yii yoo nifẹẹ si sisan owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa mọ rara.

Lori ọrọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu yii, ileeṣẹ NNPC, iyẹn ojulowo ileeṣẹ ijoba ilẹ wa to n ri si ọrọ epo bẹntiroolu, ti sọ pe owo to to irinwo biliọnu Naira (N400B) lawọn n lo lati fi sanwo fawọn oniṣowo ti wọn n lọọ gbe epo naa wa silẹ wa loṣooṣu, eyi tawọn kan sọ pe ko yẹ ko to bẹẹ rara.

Bẹẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ yii sọ pe ijọba tuntun to n bọ lọna ko gbọdọ gbiyanju lati yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu, afi ti wọn ba kọkọ pese awọn ohun ti yoo jẹ ki nnkan dẹrun fawọn mekunu daadaa ki wọn too le ṣe eleyii.

Lara ohun ti NLC sọ pe ki wọn kọkọ ṣe ni pe ki wọn jẹ ki gbogbo awọn ileeṣẹ ifọpo ilẹ wa maa ṣiṣẹ daadaa ko too di pe wọn yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu yii. Bi wọn ba kọ ti wọn ko ṣe eleyii, a jẹ pe awọn yoo ṣiwaju gbogbo oṣiṣẹ ilẹ wa pata lati bẹrẹ iyanṣẹlodi ti yoo lagbara gidi.

Latigba ti ọrọ lori yiyọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu ọhun ti n lọ nigboro lawọn kọọkan ti n sọ pe bi ijọba ba le gbiyanju lati yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu yii, o ṣee ṣe ki awọn araalu maa ra jaala epo kan (1Litre) ni ẹẹdẹgbẹrin Naira (700) tabi ju bẹẹ lọ.

Ṣa o, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ epo rọbi nile yii, (PENGASSAN) ti sọ pe awọn fara mọ ọn ki ijọba yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa kuro.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Festus Osifo, sọrọ naa di mimọ lọsẹ to kọja niluu Abuja pe ohun to daa ni bi ijọba ba le yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa, ṣugbọn ki wọn ri i daju pe wọn ṣe atunṣe sọro ileeṣẹ ifọpo ilẹ wa na, nitori nigba naa ni nnkan ko ni i nira fawọn mẹkunu pupọ.

Leave a Reply