Faith Adebọla
Lai fi ti awuyewuye nipa iyọnipo rẹ to n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) pe, Alaga apapọ PDP, Ọmọwe Iyorchia Ayu ti fọwọ sọya, o si ti fọkan awọn ololufẹ rẹ balẹ pe ni ti bawọn kan ṣe n faake kọri pe dandan loun gbọdọ fipo alaga apapọ silẹ yii, o ni ko sewu loko, afi giri aparo, ko sẹni to le yọ oun nipo naa afi b’Ọlọrun ba lọjọ pe lo ku.
Ayu ni: “Odidi lẹgbẹ PDP wa, ko si ipinya kankan. Mo n ṣe gbogbo ohun ti mo le ṣe lati ma ṣe ja ẹyin eeyan Benue ati gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ kulẹ. Tori naa, tẹ ẹ ba gbọ pe wọn fẹẹ le Ayu kuro nipo alaga apapọ, ẹ ma foya, ẹ ma mikan rara, ko sẹni to le yọ mi nipo alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu wa. Ọjọ t’Ọlọrun ba lo ya ni maa to kuro nipo.”
Asiko tawọn ara ilu rẹ lati ẹya Jemba, nipinlẹ Benue, lọọ ba a lalejo nile ẹ to wa lagbegbe Gboko, nipinlẹ ọhun, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, lo sọrọ idaniloju naa.
O ni: “Ẹ ma ṣe jẹ ki ohunkohun ko yin lọkan soke, ko sẹni to le ko ipaya ba yin. Mo fi da yin loju loni-in pe odidi kan ni ẹgbẹ oṣelu PDP wa. Ẹgbẹ to yapa ko le wọle ibo. Bo ti wu k’ẹgbẹ kan lagbara to, yoo fidi rẹmi lasiko ibo ti ko ba wa niṣọkan.
“Tori ẹ ni mi o ṣe fesi sawọn awuyewuye tẹ ẹ n gbọ wọnyẹn, ti wọn n sọ lodi si mi, tori oju lagbalagba n ya, agba ki i y’anu ni o, mi o fẹ ki ogiri ẹgbẹ wa lanu ni, ẹgbẹ ti mo wa ninu ẹ nipinlẹ mi. Ṣe ẹ mọ pe mo laṣẹ ati sọ pe lagbaja yii o le jade, tamẹdu yẹn o ni i lọ, tori ti bi mi o ba buwọ luwee iyansipo ẹ, ko sibi ti tọhun n lọ, ṣugbọn mi o ṣe bẹẹ. Gbogbo awọn oludije ti PDP fa kalẹ ni mo buwọ luwee wọn pe ki wọn tẹsiwaju ninu ilepa ati erongba wọn, atawọn ti mo nifẹẹ si o, atawọn ti mi o nifẹẹ si o, mo faṣẹ si i fun wọn. Idi ti mo si fi ṣe bẹẹ ni pe mi o fẹẹ para mi layo. Mo fẹ ki ipinlẹ Benue mupo iwaju ninu ipinlẹ ti PDP yoo ti jawe olubori ninu gbogbo ipo kawọn eeyan le ri i pe alaga ẹgbẹ wa yii gbonjẹ fẹgbẹ o gbawo bọ, gbogbo oludije PDP nipinlẹ ẹ lo gbegba oroke, ki Atiku Abubakar ko ida aadọrun-un ninu ọgọrun-un ibo aarẹ nipinlẹ wa, ki Titus Uba naa si wọle ṣọọ bii elekurọ sipo gomina lọdun 2023.
Ọlọrun lo n yan-anyan sipo oludari, o si maa n lo awọn eeyan lati gbe ẹnikan sipo olori, oun naa lo maa daabo bo tọhun. Mo fi da yin loju pe Ọlọrun lo n daabo bo mi, koda nigba to rẹra diẹ ti mo lọọ gba itọju, Ọlọrun lo pa mi mọ. Wọn ti fiya jẹ awa ẹya Tiv lọpọlọpọ lorileede yii, a o ti i ri ipin kankan gba ninu mudunmudun orileede wa, tori ẹ, imọran mi fun yin ni pe kẹ ẹ tubọ kun fun adura pe ni 2023, ki Ọlọrun gbe aarẹ to maa ṣiṣẹ pẹlu gomina ipinlẹ wa sipo, ko le wẹ omije wa nu, ko si gbọn iya to n jẹ wa kuro.
“Mo dupẹ gidigidi lọwọ ẹyin eeyan mi fun ifẹ tẹ ẹ ni si mi. Lati bii ọgbọn ọdun sẹyin ti mo ti wa nidii oṣelu, ẹ o pa mi ti ri, gbogbo igba lẹ n ti mi lẹyin. Wọn ni wolii ki i lọla niluu ẹ, ṣugbọn bii temi kọ. Ori mi wu, mo dupẹ mọ tọpẹ du lọwọ yin o,” bẹẹ ni Ayu kadii ọrọ rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, titi dasiko yii ni awọn gomina kan lẹgbẹ oṣelu PDP, titi kan gomina ipinlẹ ipinlẹ Benue nibi ti Ayu ti wa, Samuel Ortom, taku pe awọn o ni i ṣatilẹyin kankan fun oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu wọn, Alaaji Atiku Abubakar, afi bi Ayu ba kuro nipo alaga apapọ ẹgbẹ. Wọn ni aidọgba ati ojooro ni ki Atiku wa lati iha Oke-Ọya orileede yii, ki alaga apapọ naa tun jẹ eeyan Oke-Ọya kan naa. Gomina Nyesom Wike tipinlẹ Rivers lo lewaju awọn to faake kọri yii, nigba ti Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, tipinlẹ Ọyọ,