Adewale Adeoye
Gomina ipinlẹ Kano, Alhaji Abdullahi Ganduje, ti sọ pe ko si ani-ani kankan nibẹ rara pe iṣakooso Aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bii olori orileede yii lo daa ju lọ, to si jẹ pe iṣakooso rẹ paapaa ti gbe awọn araalu yii debute ayọ, ko si si aarẹ kankan to ti i ṣe gudu-gudu meje, ohun yaaya mẹfa ti Buhari ṣe lakooko iṣakooso rẹ gẹgẹ bi olori orileede yii fọdun mẹjọ gbako to fi wa nipo ọhun.
Gomina Ganduje sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lakooko to n ṣi ọgba ẹwọn igbalode oniyara ẹgbẹrun mẹta kan tijọba Buhari ṣẹṣẹ kọ pari sagbegbe Janduza, nipinlẹ Kano.
Akowe agba ijọba ipinlẹ Kano, Alhaji Usman Alhaji, to ṣoju Gandujẹ nibi eto pataki ọhun sọ pe lara pe Aarẹ Buhari ti mu gbogbo ileri rẹ ṣẹ patapata lo ṣe tun pari kikọ ọgba ẹwọn igbalode naa sinu ilu ọhun, ti aimọye iṣẹ idagbasoke gbogbo si n lọ kaakiri origun mẹrẹẹrin orileede yii.
Ninu ọro rẹ, gomina Gandujẹ ni, ‘Inu mi dun gidigidi lati sọ fun yin pe lara awọn iṣẹ idagbasoke bii mẹrin ti wọn n ṣi loni-in yii, mẹta lara rẹ lo jẹ pe inu ipinlẹ yii ni wọn wa, eyi jẹ apẹẹrẹ awọn ohun rere ti Aarẹ Buhari ṣeleri rẹ fawọn araalu Kano nigba to n ṣepolongo ibo rẹ pe oun yoo se fun wọn. Awọn araalu naa lo duro ti i gbaagbaagba ni gbogbo igba to fi n lakaka lati di aarẹ orileede yii. Ko sigba to maa gbe apoti ibo nigba naa lọhun-un ti wọn ki i dibo fun un. O ni pẹlu awọn iṣẹ idagbasoke gbogbo ti Aarẹ Buhari ṣe sinu ilu naa bayii, o han pe ipinlẹ Kano yoo tun tẹsiwaju si i ninu ohun gbogbo niyẹn.