Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Lọsẹ to kọja yii ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, pepade awọn alẹnulọrọ ninu lilo tewe-tegbo ilẹ wa fun iwosan si gbọngan Iṣẹmabaye ‘June 12’ to wa ni Kutọ, l’Abẹokuta. Nibẹ ni Araba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ti jẹ ko di mimọ pe nnkan ti n sọnu nilẹ Yoruba, paapaa awọn nnkan iṣẹdalẹ, o si ṣe ni laaanu pe a o fura.
Oloye Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe ko si aisan naa ti ewe ategbo ti Ọlọrun fun ilẹ Yoruba ko gbọ, ṣugbọn awọn eeyan ko kọbi ara si i mọ. O ni oogun oyinbo to jẹ to ba wo aisan kan, yoo ko wahala mi-in ba ara ni wọn n fowo gọbọi ra, ohun to si n fa iku aitọjọ fawọn mi-in niyẹn.
Nigba to n ṣalaye lori awọn nnkan ti Yoruba n sọnu, baba onifa naa sọ pe ede Yoruba ti a n sọ paapaa le lọ si okun igbagbe, nigba ti awọn eeyan ko ba sọ ọ mọ, nitori ede oyinbo lo ku ti ọpọ obi n sọ si awọn ọmọ wọn nile bayii. Bẹẹ, wọn ti n sọ Yoruba ni Brazil, Trinidad ati Tobago, ṣugbọn awa ti a ni ede naa ko fi yangan mọ, bii pe ohun to jẹ tiwa ko wu wa mọ la n ṣe.
O fi kun un pe kawọn to n fi tewe-tegbo ṣewosan lọọ kọ ewe nibi to ti n jẹ, ki wọn si ma ṣe ohun ti wọn ko mọ loogun fawọn eeyan, ko ma baa di pe ijọba n le wọn kiri.
Ninu ọrọ Gomina Dapọ Abiọdun, ẹni ti Igbakeji ẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ, ṣoju fun, o rọ awọn to n fi tewe-tegbo ṣewosan pe ki wọn mọ iṣẹ ti wọn n ṣe naa dunju, ki wọn ma si faaye gba awọn aṣawọ, nitori ẹmi ṣe koko.