Ko si olori gidi kan to maa lọ fun isinmi lakooko to ba n sin ilu lọwọ -Peter Obi

Adewale Adeoye

Ondije dupo aarẹ orileede yii ninu ibo gbogbogboo to waye lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu keji ọdun yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ‘Labour Party’ LP, Ọgbẹni Peter Obi ti sọkọ ọrọ lu aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibọ yan nilẹ wa, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu nipa bo ti ṣe lọọ fun isinmi ọlọjọ gbọọrọ kan lẹyin tawọn ajọ INEC, kede rẹ pe oun lo jawe olubori ninu eto idibo to waye laipẹ yii nilẹ wa. Obi ni olori gidi kan ki i lọ fun isinmi ọlọjọ gboọrọ kankan rara paapaa lakoko to n ba sin orileede rẹ lọwọ.

Obi ju oko ọrọ ọhun si Tinubu, lọjọ Monde ọsẹ yii lakoko to n ba awọn ẹlẹsin Musulumi kan ti wọn jẹ ẹya Ibo sọrọ ninu, Mọṣalaṣi gbogbogboo kan ti won n pẹ ni ‘Akwa Central Mosque’ lọjọ Mnde ọsẹ yii.

Ninu ọro rẹ lo ti sọ pe ‘ ẹni to ba mọ pe oun fẹẹ sinmi, ko maa lọọ sile rẹ lati lọọ sinmi, olori gidi kan ki i lọọ fun isinmi rara paapaa lakooko to ba n sin ilu baba rẹ lọwọ. ẹni ki wọn lọọ sinmi nile wọn, emi o nilo lati sinmi rara, gbogbo ibi ni maa de pata lati fi ifẹ han si awọn eeyan mi, mo ti lọọ ṣẹ abẹwo si awọn ọmọ ileewe, ati awọn kan ti wọn wa lọsibitu, awọn eeyan mi lawọn eeyan yii, mo ni lati maa bẹ wọn wo nigba gbogbo ni.

A maa lọọ kaakiri lati maa ṣabẹwọ sawọn ibi gbogbo, ta a mọ pe wọn ti nilo wa, ko ni i su wa rara, olori gidi to fẹẹ sin ilu, ko gbọdọ sọ pe oun n lọọ fun ara ni isinmi ọlọjọ gbọọrọ rara, paapaa ju lọ, nigba to ba n sin ilu baba rẹ lọwọ.

Bẹẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun yii ni Tinubu ti kuro nilẹ yii lọọ siluu Faranse lati lọọ fun ara rẹ ni isinmi daadaa lẹyin gbogbo wahala to ṣe lakooko ipolongo ibo gbogbogboo to waye laipẹ yii.

Tinubu ti pada de silẹ wa lọjọ Monde ọsẹ yii, o ti ṣeleri pe oun ti ṣetan bayii lati sin ilu ati lati gbe ilẹ wa de ebute ay.

Leave a Reply