Ko si orileede to le dagbasoke lai si atilẹyin awọn eeyan inu rẹ – Arẹgbẹṣọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti ke si gbogbo awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lori ọna lati ṣẹgun wahala aisi eto aabo lorileede yii.

Arẹgbẹṣọla ṣalaye pe ijọba nikan ko le ja ija naa lajayọri lai si atilẹyin awọn eeyan agbegbe kọọkan nibẹ nitori tolori-tẹlẹmu lo ni ipa lati ko lori ipese aabo fun ẹmi ati dukia wọn.

Lasiko to n gba ami-ẹyẹ latọwọ Ẹgbẹ Atunluṣe Ilẹ-Ijeṣa lopin ọsẹ to kọja ni minisita sọrọ naa.

Arẹgbẹṣọla, ẹni ti Oludamọran lori eto iroyin rẹ, Ọgbẹni Ṣọla Faṣure, ṣoju fun sọ pe diẹdiẹ, orileede yii ti n bọ lọwọ ogun igbesunmọmi ati aisi eto aabo to peye.

O fi da gbogbo awọn ọmọ orileede yii loju pe iṣẹjọba Aarẹ Muhammadu Buhari yoo gbe ijọba alaafia ati eyi to kun fun ọrọ kalẹ fun aarẹ to n bọ.

Gomina nigba kan ri nipinlẹ Ọṣun ọhun dupẹ lọwọ awọn ọmọ Ẹgbẹ Atunluṣe Ilẹ-Ijeṣa fun ipa takuntakun ti wọn ti ko lori idagbasoke ilẹ Ijesa lati nnkan bii ọgọrun-un ọdun ti wọn ti da a silẹ, o ni ko si orileede to le dagbasoke lai si atilẹyin awọn eeyan inu ẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ojuṣe gbogbo wa ni ọrọ eto aabo. A ko gbọdọ fi silẹ sọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo nikan. Ẹnikọọkan, agbegbe kọọkan, ilu ati ipinlẹ lapapọ la gbọdọ ji giri si ọrọ eto aabo.

“A gbọdọ ṣatilẹyin fun awọn oṣiṣẹ alaabo wa, ti a ba da a da wọn, ọrọ yii ko le yanju. Ijọba yoo ko ipa tirẹ, awọn oṣiṣẹ alaabo yoo ko ipa tiwọn, awa araalu naa gbọdọ ko ipa tiwa. A gbọdọ joye oju lalakan fi n ṣọri, ka tete fi irin regberegbe lagbegbe wa to awọn agbofinro leti”.

Nigba to n sọrọ nibi eto naa, alaga Ẹgbẹ Atunluṣe Ilẹ-Ijeṣa, Ọjọgbọn Olubunmi Adeniyi Obe, gboṣuba fun Arẹgbẹṣọla fun ipa to ti ko lori idagbasoke ilẹ Ojeṣa, o ni minisita naa yọ si ami-ẹyẹ ọhun.

Obe ṣalaye pe gbogbo igba ni Arẹgbẹṣọla maa n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ naa, o si ṣe gudugudu meje lori idasilẹ fasiti kan ti wọn da silẹ niluu Ileṣa. O ni aimọye awọn ileeṣẹ ijọba apapọ lo ti ṣokunfa wọn wa siluu naa.

Leave a Reply