Ko sifẹẹ laarin emi ati ọkọ mi mọ, adajọ, e tu wa ka-Adukẹ

Adewale Adeoye

‘Mo kan n gbiyanju lati nifẹẹ rẹ ni, ko sifẹẹ rẹ lookan aya mi mọ rara. Loootọ mo ti bimọ fun un, bi Ọlọrun Ọba ṣe kọ ọ niyẹn. Wọn tiẹ ti gba mi lamọran pe ka a jọọ lọọ sọ ọ nile wo boya yoo ṣee ṣe, gbogbo bi mo ṣe n ju abẹbẹ ọrọ ifẹ wa naa soke, ibi pẹlẹbẹ lo n fi lelẹ nigba gbogbo. Ẹ jẹ ki kaluku wa maa lọ lọtọotọ layọ ati alaafia bayii, ọdun kẹrinlelọgbọn ree ta a ti jọ n gbe papọ gẹgẹ bii lọko-laya, ṣugbọn mi o ṣe mọ bayii, o too gẹ”.  Eyi lọrọ to n jade lẹnu iyawo ile kan, Abilekọ Ibrahim Adukẹ, to gbe ẹjọ ọkọ rẹ, Akanbi Ishola, lọ si kootu kọkọkọkọ kan to wa lagbegbe Igboro, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọsẹ to kọja yii.

ALAROYE gbọ pe ṣaaju ọjọ Ẹti,  Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni ẹjọ awọn ololufẹ mejeeji yii ti wa nile-ejọ ọhun, ṣugbọn ti adajọ kootu naa, Onidaajọ Abdulqadril Umar, gba awọn mejeeji nimọran pe ki wọn lọọ feegun otolo to ọrọ ija to bẹ silẹ laarin awọn mejeeji lojiji yii nile, ki wọn si mu esi wa foun,

ṣugbọn ohun to ya gbogbo awọn ero ti wọn wa nile-ẹjọ naa lẹnu ni pe Abilekọ Adukẹ to gbe ẹjọ ọkọ rẹ wa si kootu faake kọri pe afi ki wọn tu igbeyawo ọdun gbọọrọ kan to wa laarin awọn mejeeji ka nitori pe oun ko nifẹẹ ọkọ oun mọ rara.

Bi adajọ ba gbe ọrọ naa gba ọtun boya wọn le ri i pari, ṣe niyawo aa tun gba osi yọ. Nigba ti ọrọ ọhun ko si fẹ tete yanju, ti akoko si n lọ, lo mu ki adajọ ile-ejọ naa beere ọrọ lẹnu ọkọ, ti ọkọ si juwọ ifẹ to wa laarin rẹ ati iyawo rẹ yii silẹ pe ko maa lọ.

Adajọ waa kilọ fun Adukẹ pe ko sera-ro fun oṣu mẹta gbako ko too di pe yoo lọ sile ọkọ mi-in, iyẹn bo ba ni i lọkan lati tun fẹ okunrin mi-in. O ni gẹgẹ bíi ohun ti ofin ẹsin Islam wi, obinrin to ba kọ ọkọ rẹ silẹ gbọdọ duro fun oṣu mẹta gbako, eyi tawọn aafaa n pe ni ‘Iddah’ ko too di pe o lọọ fẹ ọkunrin mi-in.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Umar sọ pe ki Adukẹ to gbe ẹjọ ọkọ rẹ wa sile-ẹjọ maa ṣetọju awọn ọmọ to wa laarin igbeyawo wọn, ki Ọgbẹni Akanbi ti i ṣe okọ si maa fun wọn ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounjẹ awọn ọmọ naa, ko si tun maa sanwo ileewe wọn atawọn ohun gbogbo ti wọn ba nilo pata.

Lopin ohun gbogbo, adajọ so pe ki Adukẹ maa faaye gba ọkọ rẹ nigba yoowu to ba ti fẹẹ waa wo awọn ọmọ to wa laarin awọn mejeeji yii, niwọn igba to ba ti n ṣojuṣe rẹ lori wọn nigba gbogbo. 

O  tu igbeyawo awọn mejeeji ka loju-ẹsẹ, o si ni ki kaluku wọn maa lọ sile layọ ati alaafia.

Leave a Reply