Florence Babaṣọla
Ọmọkunrin kan, Ayọọla Ọlalekan, lo ti jẹwọ bayii pe iṣẹ jibiti ori ẹrọ ayelujara ti oun n ṣe ko ni oogun ninu rara, aanu ati igbagbọ ninu Ọlọrun nikan loun maa n beere fun ti gbogbo nnkan fi maa n lọ geere fun oun.
Lasiko ti Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, n ṣafihan Ọlalekan ati aburo rẹ, Tunde, pẹlu awọn ikọ adigunjale marun-un mi-in niluu Oṣogbo llọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lọmọkunrin naa sọ pe nigba ti ileewe su oun, ti iṣẹ-kikọ naa si nira ju foun, loun bẹrẹ iṣẹ ‘yahoo-yahoo’.
Ọlalekan ṣalaye fun ALAROYE pe oun ki i jale, bẹẹ ni toun yatọ si eyi ti wọn n pe ni ‘Yahoo-plus’, ti wọn maa n tẹ nidii pẹlu oogun owo, o ni oun ko tẹ ẹ nidii ni toun, ṣugbọn ohun kan ṣoṣo ti oun maa n beere ninu adura nigbakuugba ti anfaani rẹ ba yọ ni aanu Ọlọrun, oun si nigbagbọ ninu Ọlọrun pe iṣẹ naa yoo yọwo fun oun.
Ọlalekan, ọmọ bibi ilu Ibadan, ti inagijẹ rẹ n jẹ Wire Lord sọ pe ko si inu akanti ti oun ko ti le ko owo jade niwọn igba toun ba ti ri siimu ti ẹni naa fi n gba alaati, nitori gbogbo boun ṣe le mọ nipa ẹni to ni siimu loun ti kọṣẹ rẹ ni Mushin, niluu Eko.
O fi kun ọrọ rẹ pe oun maa n ri owo daadaa ninu iṣẹ naa, o si jawo fun oun ju iṣẹ ‘yahoo’ gan-an ti ọpọlọpọ ọdọ n ranju mọ lasiko yii lọ.
Yatọ si iṣẹ waya-waya ti Ọlalekan n ṣe, o ni oun tun ni talẹnti orin, ti oun si ti ṣe orin kan sori ẹrọ-ayelujara laipẹ yii to pe orukọ rẹ ni Wire 999.
Ninu ọrọ kọmiṣanna ọlọpaa, o ni loootọ ni Ọlalekan ko ba wọn digunjale, ṣugbọn oun lo n ba wọn ko owo to ba wa lori siimu foonu ti wọn ba gba lọwọ awọn ti wọn ba lọọ digun ja lole.
Ni ti Tunde, aburo Ọlalekan, Ọlọkọde ṣalaye pe ọmọ ẹkọṣẹ lọmọ naa jẹ labẹ ẹgbọn rẹ, ṣe loun naa n kọ bi wọn ṣe le ko owo lakanti lai jẹ pe ẹnikẹni fura si wọn.
Lara awọn ti wọn ṣafihan papọ mọ Ọlalekan ni Adewusi Iṣọla, Moshood Yusuf, Taye Fala, Azeez Dauda ati Abdullahi Adeṣọkan.
Ọlọkọde sọ pe iwadii n tẹ siwaju, ati pe ni kete tiwadii ba ti pari ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.