Kobooko awọn aafaa lo mu mi sa nile kewu-Ọbasanjọ

 Gbenga Amos, Abẹokuta

Aarẹ orileede Naijiria tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe bi iba ti dun mọ oun lati kọ alukuraani to, ẹgba ti awọn aafaa maa n na awọn ọmọ kewu lo mu oun sa nidii rẹ.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo sọrọ naa lasiko ifilọlẹ ati wiwe lawani fun Sheik Salis Adenẹkan gẹgẹ bii Olori ẹsin ijọ Tijaniyyah fun gbogbo ilẹ Yoruba ati ipinlẹ Edo, eyi to waye niluu Abẹokuta.

O ni, ‘‘Mo ti sọrọ yii ni aimọye igba pe nigba ti mo wa ni kekere, kobooko ni ko jẹ ki n le kọ kewu daadaa. Ṣugbọn pẹlu rẹ naa, mo ṣi ranti awọn orin ti a maa n kọ.’’

Ninu ọrọ rẹ lo ti ni, ‘mo wa sibi yii lati ki yin, ohun ti a waa ṣe lonii yii da lori ẹsin. Ọkan ninu erongba wa naa si ni pe ta a ba ṣe ohun gbogbo tan laye yii ta a ku, ki a le ri alijanna wọ’’.

O ni ẹnikẹni to ba n ronu nipa ọrun gẹgẹ bii ile ikẹyin ko ni i fi ẹsin tabi igbagbọ rẹ sere nigba to ba wa laye.

Ninu ọrọ iyanju rẹ, gbajumọ oniwaasi nni, Sheik Sulaimon Onikijipa, rọ awọn aladari lati ṣọra fun aṣilo agbara nitori wọn yoo jiyin bi wọn ṣe lo agbara ti Ọlọrun fun wọ. Bẹẹ lo rọ awọn ọmọ ijọ Tijaniyyah lati wa ni iṣọkan.

 Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, ẹni ti Olori awọn oṣiṣẹ rẹ, Shuaib Salis, ṣoju fun rọ awọn Musulumi lati ri i pe wọn ṣe ojuṣe wọn gege bii ọmọ ilu lasiko idibo ọdun to n bọ, ki wọn si ri i pe aṣiwaju to le mu ilọsiwaju ba orileede yii ni wọn dibo yan.  

Leave a Reply