Faith Adebọla
O jọ pe awọn to n gbe oogun oloro ṣẹṣẹ kasa ki wọn maa gbe egboogi naa sinu bata ni bayii, nitori ko pẹ ti wọn mu obinrin kan, Sidikat Ajiṣegiri, pe o ko kokeeni sinu bata to n wọ lọ si Saudi, tọwọ ajọ to n gbogun ti tita ati lilo oogun oloro si tẹ ẹ. Wọn ti tun mu ọkunrin mi-in to ko ọpọlọpọ kokeeni sinu awọn bata kan to n ko lọ si orileede Saudi bayii.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla yii, ni wọn mu ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Lateef Oyenuga, ni papakọ ofuurufu ilẹ wa, Murtala Muhammed, to wa niluu Ikẹja, to ko kokeeni sinu ọpọlọpọ bata olokun dudu to ko sinu ẹru to loun n gbe lọ si ilu Jeddah, lorileede Saudi Arabia. Baalu Ethopia lo fẹẹ wọ.
Ọkan ninu awọn oṣiṣe ajọ to n gbogun ti ooogun oloro to yẹ awọn ẹru naa wo sọ pe kokeeni ti iwọn rẹ to irinwo giraamu (400g) ni wọn ko pamọ sabẹ awọn bata naa.
Nigba ti wọn fi ọrọ wa ọkunrin naa lẹnu wo, o ni ọkunrin kan torukọ re n jẹ Wasiu Sanni Gbolahan ti inagijẹ re n jẹ Teacher lo gba awọn lati maa gbe oogun oloro. O ni wọn ti kọkọ ko awọn oogun oloro kan fun oun pe ki oun tọju rẹ sinu ara, ṣugbọn nigba ti ẹmi oun ko gbe e ni ọn ni ki oun ko o sinu bata ti oun ko o si ti ọn fi mu oun yii.
Oyenuga ni ki i ṣe pe iṣẹ gbigbe oogun oloro wu oun naa, ṣugbọn oun feẹ lo owo ti oun ba ri nibẹ lati sanwo idanwo omo oun to wa ni ọdun to gbẹyin nileewe girama loun fi ba wọbn gbe e.
NDLEA ni Wasiu Sanni ti ọkunrin yii ni o ran oun niṣẹ yii ti jingiri ninu owo kokeeni. Wọn ni o ti gbiyanju lati gbe kokeeni lọ si Saudi Arabia ti Dubai. Wọn ni oun lo fa dẹrẹba BRT kan, Bọlajoko Muyiwa Babalọla le ọkunrin oloteẹli ti wọn loun naa n ṣowo oogun oloro, Alaaji Ademọla Afọlabi Kazeem lọwọ, tiyẹn fi ni ko gbe kokeni lọ si Dubai, ṣugbọn ọwọ ajọ to n gbogun ti oogun oloro tẹ ẹ lọjọ kẹtadinlogun, osu Kẹfa, ọdun yii. Ọjọ oṣu Kọkanla yii lọwọ pada tẹ Afọlabi ti ọn tun n pe ni Adekaz ni tiẹ.
Ilu Ikorodu lọwọ ti tẹ Sanni, ẹni ti wọn ni oun lo maa n ba awọn ti wọn n gbe kokeeni yii wa aọn ti wọn le ba wọn gbe e.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni ọwọ tẹ obinrin kan, Sidikatu Ajiṣegiri to ni oniṣowo aṣọ ọmọde loun niluu Eko. Inu bata ti obinrin naa wọ sẹsẹ nigba to n lọ si Saudi loun tọju kokeeni pamọ si.