Bi wọn ba n sọ pe wọn fori eeyan sọlẹ sibi kan, a jẹ pe ibẹ ni wọn bi tọhun si niyẹn. Bẹẹ lọrọ ri fun Jamiu Ọlasunkanmi Ọlabankẹwin, ẹni tawọn eeyan mọ si 100 years lagboo tiata Yoruba. Baba rẹ, Oloogbe Fasaasi Ọlabankẹwin(Dagunro), ko ti i jẹ kọmọ ọkunrin yii bẹrẹ irin ẹsẹ to ti n gbe e lọ soko ere.
Nigba ti Jamiu waa n dagba, lokeṣan naa lo ti n lo ọpọlọpọ asiko rẹ, ibẹ lo ti rin, ibẹ naa lo si lahun si. Ṣugbọn lasiko yii, o tojọ mẹta tawọn eeyan ti gburoo ọmọ naa ninu fiimu, eyi lo jẹ ki ADEFUNKẸ ADEBIYI, akọroyin AKEDE AGBAYE, fọrọ wa a lẹnu wo laipẹ yii nigba to ṣalabaapade rẹ loko ere kan.
AKEDE AGBAYE: O tojọ mẹta ta a ti gburoo yin ninu fiimu, nibo lẹ wa latijọ yii?
100 YEARS: Mo ṣi wa ninu iṣẹ tiata, mi o niṣẹ mi-in ti mo n ṣe, nitori iṣẹ ti baba fi le mi lọwọ gan-an ree. Mi o mọ iṣẹ mi-in ju tiata lọ.
AKEDE AGBAYE: Ti wọn o ba waa pe yin siṣẹ nkọ? ti ilẹ da, a si mọ pe ọmọ kekere ara yin ni yin, ki lẹ maa n ṣe niru lasiko yẹn?
100 YEARS: Ọlọrun ṣi n ṣaanu mi, nitori ẹni to ba nifẹẹ eeyan maa waayan, aa dẹ pe eeyan siṣẹ.
AKEDE AGBAYE: Awọn ere ibilẹ, ere oloogun lẹ maa n saaba ṣe. Nisinyii, ere oloogun ko fi bẹẹ si mọ, bawo lawọn ere igbalode ṣe ri lara yin?
100 YEARS: Nigba ti baba mi wa laye, ko si ipa ti wọn o fi kọ mi. Ati ibilẹ ati tigbalode, gbogbo ẹ ni wọn fi kọ mi ti mo dẹ le ṣe. Iyẹn jẹ ko rọrun fun mi lasiko yii naa to jẹ ere igbalode lo pọ ju. Gbogbo ipa ti wọn ba fun mi naa ni mo le ṣe.
AKEDE AGBAYE: Nigba ti baba ti waa ku bayii, ki lo n ṣẹlẹ lẹyin iku wọn to jẹ ka ni wọn wa laye ni, ko ni i ri bẹẹ
100 YEARS: Nnkan to n ṣẹlẹ pọ, ti mo ba ni ko pọ, irọ ni mo pa. Nitori awọn nnkan ti baba n ṣe fun mi pọ. Ti wọn ba ri tọrọ-kọbọ, wọn maa fun mi. Temi o ba ‘produce’ (ṣe fiimu), tawọn ba ṣe, wọn maa fun mi. Wọn aa ṣaa maa ran mi lọwọ pe ki iṣẹ temi naa le goke. Ṣugbọn igba ti baba ti ku, hmmmm.
O yẹ kawọn to ba nifẹẹ eeyan ran eeyan lọwọ, ṣugbọn ko si. Ẹ ṣaa jẹ ka maa woran. Lẹyin keeyan maa pe Ọlọrun, k’ Ọlọrun dẹ jẹ keeyan ri aanu gba lọdọ awọn to maa ran an lọwọ.
AKEDE AGBAYE: Se a waa le sọ pe iku baba ni ko jẹ ka ri yin ninu fiimu mọ lẹnu ọjọ mẹta yii?
100 YEARS: Iku baba kọ, iku wọn kọ rara. Keeyan ṣaa maa bẹ Ọlọrun pe ko ṣe daadaa fun wa. Ko rọrun lati ṣe fiimu lasiko yii nitori ko sowo.
Eeyan n ṣiṣẹ ko le baa rowo ni, nigba teeyan ba dẹ waa kowo le fiimu ti ko rowo ẹ pada, ṣe ẹ mọ pe ko si bi wọn ko ṣe ni i maa sọ pe o tojọ mẹta fun iru ẹni bẹẹ.
Bẹ ẹ si wa iranlọwọ lọ, awọn obinrin lawọn olowo n ṣeranlọwọ fun, k’Ọlọrun ṣaanu awa ọkunrin ni. Kẹ ẹ too ri i pe wọn ṣe ọkunrin laaanu, ọna maa jin, awọn obinrin aa ti rowo gidi gba lọ, nitori ohun ti wọn n ri gba lara obinrin tọkunrin o ni. K’Ọlọrun ṣaanu wa ni.
AKEDE AGBAYE: Awọn irun dada tẹ ẹ maa n ṣe sori pẹlu tatoo tẹ ẹ ya sara yii, ṣe ki i jẹ kawọn eeyan foju ẹni to wa lẹgbẹ buruku wo yin?
100 YEARS: Rara, wọn ti mọ pe ami idanimọ mi ni. Tẹ ẹ ba wo fiimu 100 Years, irun Dada ni mo ṣe sori nibẹ. Baba mi gan-an maa n ṣe e, awọn naa maa n dirun. Ami idanimọ lo wa fun, ki i ṣe ti ẹgbẹ buruku rara.
AKEDE AGBAYE: Iyawo meloo lẹ ni?
100 YEARS: Iyawo wa, ọmọ wa. Mo n dupẹ lori famili mi.
AKEDE AGBAYE: Ta lawokọṣe yin ninu tiata?
100 YEARS: Awokọṣe mi naa ni dadi mi, nitori lati kekere pinniṣin ni wọn ti n gbe mi lọ si lokeṣan. Ibẹ ni mo ti rin, mo laju sibẹ ni. Mi o ti i maa rin ti wọn ti n gbe mi lọ si lokeṣan.
Emi ni mo wa pẹlu Oluwẹri ninu fiimu Idagiri, wọn gbe mi dani ni, mi o ti i rin. Ko si bo ṣe wu ko ri, Dadi mi…..(o bu sẹkun).