Ọlawale Ajao, Ibadan
Ikọja aaye ti i mu ekute ile pe ologinni nija, ti sọ baba ẹni ọgọta (60) ọdun kan, Adeyẹmi Isaac Adebọla,
dero atimọle, pẹlu bo ṣe n fi iṣẹ ọlọpaa lu awọn eeyan ni jibiti nigba ti ko tilẹ ṣiṣẹ ọlọpaa rara.
Nigba ti baba naa yoo tun waa ṣe bẹbẹ lori bẹbẹ, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lo tun n pera ẹ, bi aaye ba si gba a daadaa nibomi-in paapaa, a tun maa pẹra ẹ ni igbakeji ọga agba awọn ọlọpaa patapata lorileede yii.
Ṣugbọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an, ọdun 2023 yii, ẹ̀kú ṣi kuro loju eegun, nigba ti ayederu ọga ọlọpaa naa gbalejo awọn agbofinro latọdọ CP Adebọla Hamzat, ti i ṣe ojulowo ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ.
Nigba to n ṣafihan baba onigboya naa fawọn oniroyin n’Ibadan, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe ki i ṣe pe Adebọla n pe ara ẹ lọgaa ọlọpaa nikan, niṣe lo n lo ayederu ipo rẹ wọnyi lati fi purọ gbowo lọwọ awọn alaimọkan eeyan nigboro Ibadan ati kaakiri ipinlẹ naa.
SP Ọṣifẹṣọ fìdi ẹ mulẹ pe, “ọpọ igba lawọn eeyan ti fi ọrọ ọkunrin yii to wa leti. Idi niyẹn ti CP (Adebọla Hamzat) ṣe ṣagbekalẹ ikọ awọn atọpinpin lati ṣewadii nipa ọkunrin naa’’.
O ni niluu Ọyọ ni wọn ti lọọ mu un, to si jẹwọ pe loootọ loun n fi ipo awọn lọgaalọgaa lẹnu iṣẹ ọlọpaa tan awọn eeyan jẹ nigba ti ki i ṣe pe oun tilẹ ṣiṣẹ ọlọpaa ri rara.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ti jẹwọ pe loootọ loun maa n pera oun lọgaa ọlọpaa lai figba kankan ṣiṣẹ ọhun ri, ṣugbọn oun ki i fi i lu awọn eeyan ni jbiti, bi ko ṣe lati fi ran wọn lọwọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ẹẹmẹrin pere ni mo ti fi ipo ọga ọlọpaa ran awọn eeyan lọwọ, ṣugbọn o ya mi lẹnu pe awọn ti mo ṣoore fun yẹn ko mọyi oore.
“O tiẹ to wẹda mi, lọjọ to ni wahala pẹlu awọn ọlọpaa, ti wọn ti i mọle ni teṣan ọlọpaa Challenge, n’Ibadan, emi ni mo gba a silẹ nigba ti mo pe teṣan ọlọpaa yẹn, ti mo si sọ pe emi AIG (igbakeji ọga agba ọlọpaa lorileede yii) ni mo n ba wọn sọrọ.
Laipẹ ni wọn yoo foju afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ gẹgẹ bi alukoro awọn ọlọpaa ṣe fidi ẹ mulẹ.