Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Latari bi awọn to n lugbadi arun Korona ṣe n pọ si i lojoojumọ nipinlẹ Ọṣun, ijọba ti paṣẹ bayii pe ko ni i si ipejọpọ fun ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo lọdun yii.
Kọmisanna fun ọrọ aṣa ati ibudo igbafẹ, Ọnarebu Ọbawale Adebisi, lo gbe atẹjade naa sita. O ni ki onikaluku fidi mọle rẹ, awọn olubọ-Ọṣun atawọn tijọba ba fun lanfaani nikan ni wọn yoo lanfaani lati lọ soju odo Ọṣun.
Ọbawale ṣalaye pe awọn eeyan perete ti wọn n lọ si odo Ọṣun gan-an gbọdọ ṣe gbogbo nnkan wọn nibaamu pẹlu ilana tijọba gbe kale lati dena arun Korona.