Ọlawale Ajao, Ibadan
Aja to bu ọmọ olowo ẹ jẹ, to waa lọọ sapamọ sidii Ògún, oun funra rẹ ti ṣedajọ ara ẹ. Bó ṣe rí gan-an niyẹn fun ọkunrin afurasi ole kan, Ogunṣẹyẹ Kẹhinde, ẹni to jale ninu kootu, nibi ti wọn yoo ti tete ran an lọ ṣewọn ọlọdun gbọọrọ lai ṣe wahala.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii, lọwọ tẹ ọkunrin naa nibi to ti n ji batiri yọ ninu mọto onimọto ti wọn paaki sinu ọgba ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan.
Oṣiṣẹ kootu ọhun kan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ, ṣugbọn ti ko darukọ ara ẹ fakọroyin wa fidi ẹ mulẹ pe ọkan ninu awọn ọdẹ to n ṣọ inu ọgba kootu ọhun lo ka ogboju afurasi ole yii mọ idi iwa ọdaran naa.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọpọ igba lọkunrin yii ti maa n yọ batiri ninu mọto onimọto bẹẹ, to si maa n ta a fun gbajumọ oniṣowo batiri ọkọ kan lọja Ogunpa, n’Ibadan.
Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ kootu ọhun ṣalaye f’akọroyin wa pe “Ọrẹ mi to jẹ ọkan ninu awọn ọdẹ to n ṣọ ọgba yii lo ka a mọbi to ti n jale yẹn ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ijẹta (Mọnde).
“O ni ko sẹni to maa ri ọkunrin yii to le ronu pe ole lo n ja, nitori o mura daadaa, aṣọ dudu ati funfun lo wọ, lọọya leeyan yoo pe e, nitori bi awọn lọọya ṣe maa n mura lo ṣe mura.
“Ṣadeede ni mo ri i to yọ kọkọrọ kan jade ninu apo ṣokoto ẹ, to si ṣilẹkun, to tun ṣi bọnẹẹti ọkọ yẹn. Lẹyin naa lo yọ batiri inu mọto yẹn. Eeyan maa ro pe oun lo ni mọto yẹn ni, nitori niṣe lo fi kọkọrọ to mu dani ṣi i lọwọ kan lai gba a lasiko rara.
“Lẹyin to yọ batiri yẹn tan, o bẹrẹ si i gbe e jade lọ, iyẹn (ọdẹ) ni ki ni batiri ọkọ n wa lọwọ ẹ, o loun loun ni in.
“Ṣugbọn nigba ti Ọlọrun yoo mu un, ọkan ninu awọn oṣiṣẹ kootu yii naa ti ọdẹ mọ daadaa lẹni to ni mọto yẹn. Biyẹn ṣe pe awọn alakooso kootu niyẹn ti wọn fi fi ankọọbu si i lọwọ.
“Lati ijẹta yẹn la ti fa a le ọlọpaa lọwọ ni teṣan ọlọpaa to wa l’Oluyọle, n’Ibadan.
Nigba to n dahun ibeere awọn to mu un ninu ọgba ile-ẹjọ naa ninu fidio kan to ti gba ori ẹrọ ayelujara kan bayii, Kẹhinde sọ pe dẹrẹba ọkọ loun, ṣugbọn oun ko ri mọto kankan wa bayii.
O ni iṣẹ awakọ naa loun wa lọ sileewosan Adeọyọ, n’Ibadan, ti wọn fi beere iwe aṣẹ iwakọ oun, nitori pe oun ko ni iwe naa loun ṣe lọọ ji batiri ọkọ yọ ki oun le ri owo ṣe iwe iwakọ.
Bo tiẹ jẹ pe wọn lo ti to batiri bii mẹfa ti wọn ti yọ nínú ọgba kootu naa, Kẹhinde, ẹni to n gbe ile awọn obi ẹ laduugbo Apata, n’Ibadan, sọ pe igba akọkọ ree ti oun yoo ji batiri ọkọ yọ nibẹ.
Njẹ bawo lo ṣe ri ilẹkun ọkọ naa ṣi, ọkunrin to ṣee ṣe ko ti le lẹni ọgbọn ọdun yii dahun, o ni, “Mo ni kọkọrọ kan ti mo fi maa n ṣi awọn ikẹkun mọto lọwọ”.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana la gbọ pe wọn ṣedajọ afurasi ole yii ni yara igbẹjọ kan ninu ọgba kootu kan naa to ti huwa ẹṣẹ, loju ẹsẹ ladajọ si ti ni ki wọn fi i pamọ sinu atimọle titi ti idajọ gan-an yoo fi waye lori ẹsun ole ti wọn fi kan an.