Jọkẹ Amọri
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko ṣi n daro iku alaga wọn, to tun jẹ oludari agba nileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Santa Maria Hospital, Dokita Dominic Adegbọla, ti wọn ni arun to ni i ṣe pẹlu Korona lo pa a l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Alukoro ẹgbẹ naa, Gani Taofik, lo kede iku ọkunrin to pe ni ẹlẹyinju aanu to n fowo rẹ ṣaanu fawọn to ku diẹ kaato yii.
Gani ṣapejuwe Adegbọla bii oloṣelu kan to ni ifẹ awọn eeyan ẹsẹ kuku lọkan, to si maa n ṣaanu fun wọn.
O ṣe diẹ ti oloogbe yii ti n kopa ninu ọrọ oṣelu nilẹ wa, lati aye Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ni. O si ti dupo gomina ri labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APGA.