Olori ijọba ile Ghana tẹlẹ, Ọgagun Jerry Rawlings, ti ku o. Arun korona lo pa a loni-in yii gan-an, ọmọ ọdun mẹtalelaadọrin (73) si ni. Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ni pe ko ti i ju oṣu kan lọ to ṣẹṣẹ sin oku iya rẹ, n loun naa ba tun tẹri gbaṣọ.
Ko sẹni ti yoo pe oun ko gburoo Rawlings ni bii ogoji ọdun sẹyin nigba to gbajọba ilẹ Ghana, gẹgẹ bii ologun, to si foju awọn oṣelu jẹgudujẹra orilẹ-ede naa ri mabo. Ọsan gangan ọjọ kan lo ni ki wọn pa awọn olori ijọba tẹlẹ nibẹ, nitori pe wọn ko owo ilẹ Ghana jẹ, ti wọn si sọ awon ọmọ Ghana di alarinkiri ati atọrọjẹ kari aye. Ki Rawlings to pada gbejọba naa silẹ, nnkan ti yipada ni Ghana, awọn ọmọ orilẹ-ede naa ti wọn sa lọ sẹyin odi si ti pada wale.
Lẹyin to gbe ijọba orile-ede naa silẹ paapaa, ọkan ninu awọn tawọn eeyan fẹran ju, ti wọn si bọwọ fun julọ ni Afrika ni Rawlings i ṣe, bo ba si sọrọ gbogbo aye ni fara balẹ gbọ ọ. Afi bii korona ṣe ki i mọlẹ lojiji, arun naa ko si fi i silẹ titi to fi pa a.