Kudi loun fẹẹ k’ọkọ l’Abẹokuta, o lọkunrin naa n yan ale, ko si tọju oun atawọn ọmọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi nnkan ko ba ṣe ẹṣẹ, ẹṣẹ ki i deede ṣẹ. Ohun ti Kudirat Wasiu, obinrin to ti lo ọdun mẹẹẹdọgbọn (25 years)  nile ọkọ rẹ to n jẹ Jimọh Wasiu, sọ fun kootu Ake ree, l’Abẹokuta, nigba ti wọn n beere pe ki lo de to fẹẹ kọ ọkọ to bimọ marun-un fun pẹlu bii ọjọ ṣe ti lọ lori igbeyawo wọn.

Kudi ṣalaye fun kootu lọsẹ to kọja, o ni lasan kọ loun wa sile-ẹjọ pe ki wọn tu oun ati ọkọ oun ka, obinrin yii sọ pe Jimọh n fiya jẹ oun atawọn ọmọ ni.

O tẹsiwaju pe ọdun marun-un sẹyin lọkọ oun bẹrẹ iwakiwa, to di pe o n yan ale, ti ko si fi bo foun rara.

O ni nigba to bẹrẹ ale yiyan  naa ni ko tọju oun atawọn ọmọ marun-un tawọn bi mọ, igba naa ni ko beere ohun ti wọn n jẹ ti ko si sanwo ileewe wọn mọ.

Bakan naa lo ni bawọn ba ja bayii, niṣe ni Jimọh yoo maa dunkooko mọ oun, ti yoo sọ pe oun yoo pa oun danu. Bẹẹ, ọti to n mu kiri lo tun fa a to fi bẹrẹ si i ṣe bii pe ki i ṣe ọkunrin toun bi gbogbo ọmọ fun naa kọ yii.

Nigba ti yoo tilẹ fiya naa jẹ oun tan pata, Kudi ni niṣe lọkọ oun le oun jade pẹlu awọn ọmọ, ti ko tiẹ beere ibi tawọn n sun tabi ohun ti awọn n jẹ.

Ile awọn mọlẹbi atawọn eeyan ti wọn ni aanu loju lo ni awọn n ya sun, ti ko si si ifọkanbalẹ foun atawọn ọmọ naa. Awọn ọmọ ọhun ti dagba bi Kudi ṣe wi, wọn ti n wa bi yoo ṣe daa funra wọn. Eyi to kere ju ninu wọn ti wọn n pe ni Zainab ti pe ọdun mejidinlogun (18), bẹẹ ni kaluku wọn ṣe n fori kọ kiri. Obinrin yii sọ pe o ti le loṣu meji bayii ti ọkọ oun ti awọn jade.

Fun awọn idi yii, Kudi ni oun fẹ ki kootu lo agbara ofin lati fagi le igbeyawo oun ati Jimọh, koun kuku mọ pe oun ko lọkọ mọ.

Nigba to n fesi, Ọgbẹni Jimọh Wasiu ni oun ko le iyawo oun jade nile, funra ẹ lo lọ tọmọtọmọ.

Jimọh sọ pe ẹru iyawo oun ṣi wa nile oun, iba diẹ lo mu lọ nigba to n lọ, ohun ti kootu yoo fi mọ pe oun ko le e jade niyẹn.

O ni to ba jẹ Kudi ṣi fẹẹ pada wa sile ko maa waa ṣeyawo oun lọ, aaye wa, oun ṣi nifẹẹ rẹ. Bo ba si ni oun ko wale mọ, ko si wahala, oun naa yoo mu ifẹ rẹ kuro lọkan oun kia, ki kootu ṣe ohun to fẹ fun un.

Jimọh ni ẹlẹjọ ṣa eyi to dun ro niyawo oun yii, o ni ṣe oun naa ko maa gba aleebu Kudi mọra fọdun mẹẹẹdọgbọn ni, abi Kudi funra ẹ yoo sọ pe oun ko mọ pe oniwahala obinrin loun. O ni oun lo maa n fa a tawọn fi n ja, oun ko si tori ẹ le e jade, funra ẹ lo lọ.

Aarẹ A. O Abimbọla lo gbọ ẹjọ naa, o ni oun ko ni i tu wọn ka kia bayii, ki wọn tun pada wa si kootu, kawọn agbaagba tun yẹ ọrọ naa wo, boya yoo pada ṣee sọ nitubi-inubi.

Leave a Reply