Ibrhim Alagunmu, Ilọrin
Oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo gbogbogboo ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun ta a wa yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti juwe ipinlẹ Kwara gẹgẹ bii eyi to ti gba ominira lati ọdun 2019, ti wọn o si le tun pada soko ẹru mọ, o ni eyi ni yoo mu ki wọn tun tẹka dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC nibi eto idibo apapọ ọdun 2023.
Tinubu sọrọ yii lasiko to gbe eto ipolongo ibo rẹ wa siluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, eyi to waye ni Gbọngan Mẹtropolitan Square, lagbegbe Asa-Dam, Ilọrin, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.
Jagaban ni ayẹyẹ ominira lawọn n ṣe lonii, ati pe oun dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Kwara ti wọn nigbagbọ ninu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ti wọn fi fibo gbe e wọle lọdun 2019, ti ko si ja wọn kulẹ, to n ṣiṣẹ tọkan tara, to si ti mu oniruuru idagbasoke ba ipinlẹ naa.
O tẹsiwaju pe bi ọmọ orílẹ-ede yii ba n fẹ ayipada si rere, ogun-ibi ati ọjọ ọla to dara fun awọn ọmọ wọn, o ni ko tun sọna abayọ mi-in to ju pe kawọn eeyan fi ibo wọn gbe oun wọle sipo aarẹ lọ, ki wọn si dibo fun gbogbo oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC patapata.
Lara awọn to peju peju sibi eto ipolongo ibo ọhun ni: Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ati iyawo rẹ Ambassadọ Olufọlakẹ ÀbdulRazaq, Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima; oludari ipolongo ibo aarẹ Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong; Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sanni Bello; Igbakeji Gomina ipinlẹ Kwara, Kayọde Alabi; alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC nilẹ yii, Abdullahi Adamu; Abẹnugan ileeasofin tẹlẹ, Dimeji Bankọle:, awọn sẹnetọ, to fi mọ sẹnetọ mẹtẹẹta ni Kwara, awọn aṣoju-ṣofin, minisita lẹka ibanisọrọ ati aṣa nilẹ yii, Lai Mohammed atawọn agba oloṣelu mi-in.