Laarin oṣu meji, Ọọni Ogunwusi ṣe mọmi-n-mọ-ọ fun olori mẹrin

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iwadii Alaroye ti fi han bayii pe, o kere tan, obinrin mẹrin ni awọn mọlẹbi Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti lọọ ṣe mọmi-n-mọ-ọ fun. Bi ohun gbogbo ba si lọ bo ṣe yẹ, awọn mẹreerin ni wọn yoo di Olori laafin kabiyesi, ṣugbọn ko ti i sẹni to le sọ ọjọ ti eleyii maa waye.

Ibẹrẹ oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Mariam Anako to jẹ ọmọ bibi Ẹbira, nipinlẹ Kogi, wọle tilu-tifọn, oun lo si jokoo ti kabiesi lasiko ayajọ ọdun Ọlọjọ ti wọn ṣe kọja niluu Ileefẹ.

Opin ọsẹ yii la gbọ pe wọn yoo mu obinrin miiran, Afọlaṣhade Ashley Adegoke toun jẹ ọmọ bibi ilu Ileefẹ, wọ aafin Ọọni ni Ẹnuwa.

Bakan naa la gbọ pe laarin oṣu to kọja si oṣu yii, awọn mọlẹbi kabiesi ti lọọ tọrọ Elizabeth Ọpẹoluwa Akinmuda ati Oluwatobilọba Abigail Philipps, lọwọ awọn mọlẹbi wọn.

 

Bo tilẹ jẹ pe wọn ṣẹṣẹ lọ n ṣe idana awọn olori yii ni, a gbọ pe wọn ti n ṣe wọle-wọde pẹlu Ọba Ogunwusi tẹlẹ, bẹẹ ni awọn mẹrẹẹrin si ti mọ ara wọn, idi niyi ti ko fi jọ Olori Mariam loju nigba ti awọn oloye sọ fun un lọjọ ti wọn mu un wọ aafin pe oniyawo pupọ ni Ọọni.

A oo ranti pe ọdun 2021 ni Naomi Ṣilẹkunọla to bi ọmọkunrin kan, Tadenikawo, fun Ọọni Ogunwusi, ko ẹru rẹ kuro ninu aafin.

Leave a Reply