Faith Adebọla, Eko
Oriṣiiriṣii ọrọ ibanikẹdun lo n rọjo lasiko yii lagbo awọn oṣere tiata ilẹ wa, paapaa awọn ti elede Gẹẹsi, latari bi iku ojiji ṣe mu meji lara wọn lọ ni ṣisẹ-n-tẹle.
Ọjọbọ, Tọsidee, ni ẹni akọkọ, Ọgbẹni Victor Ọlaotan, jade laye, nileewosan kan nipinlẹ Eko nibi to ti n gba itọju.
Ba a ṣe gbọ, lati nnkan bii ọdun marun-un sẹyin lọkunrin naa ti n paara ọsibitu latari ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ si i ninu oṣu kẹwaa, ọdun 2016, nigba to n dari rele lati irinajo kan.
Latigba naa ni nnkan ko ti lọ daadaa fun Oloogbe Victor, wọn ni iṣẹ abẹ meji ọtọọtọ lo ṣe, sibẹ, ẹkọ ko ṣoju mimu lori ọrọ ilera rẹ.
Iroyin iku Victor yii ko ti i ranlẹ daadaa ti ọfọ mi-in fi wọle de lagbo tiata, Ọgbẹni Ifeanyi Dike loun naa tun fo ṣanlẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, lo ṣe bẹẹ ku patapata.
Wọn ni lati ọdun diẹ sẹyin loloogbe yii ti n ba arun jẹjẹrẹ kidinrin (kidney cancer) fa a, bo tilẹ jẹ pe aisan naa ko da a gunlẹ, titi dasiko iku rẹ yii, oun ni Alaga igbimọ aṣeefọkantan fun ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria (Board of Trustee of Actors Guild of Nigeria).
Minisita feto iroyin ati aṣa nilẹ wa, Alaaji Lai Mohammed, ti kọwe ibanikẹdun sawọn mọlẹbi tiṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si, bẹẹ lo ba awọn oṣẹre tiata daro, o ki wọn kuu ara fẹra ku.