Laarin wakati mẹrinlelogun sira wọn, rẹfiri meji ku lojiji nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Meji ninu ọmọ ẹgbẹ NRA (Nigeria Refrees’ Association), iyẹn ẹgbẹ awọn adari ere bọọlu alafẹsẹgba lorileede yii, ẹka tipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Rafiu Ọpẹyẹmi ati Ibikunle Abiọdun, ni wọn ti jẹ Ọlọrun nipe laarin wakati mẹrinlelogun sira wọn.

Ohun to jẹ ki iku wọn ya ọpọ eeyan lẹnu ni pe laarin wakati mẹrinlelogun ni awọn mejeeji dagbere faye sinu iṣẹlẹ ọtọọtọ.

Lopin ọsẹ to kọja yii, iyẹn laarin ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadilelogun (17), oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, si ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, lawọn rẹfiri mejeeji ti wọn jẹ ara ipinlẹ Ọyọ yii padanu ẹmi wọn.

Ọgbẹni Ibikunle Abiọdun, ẹni to jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn rẹfiri l’Akinyẹle, n’Ibadan, lo kọkọ jade laye laaarọ ọjọ Jimọ, lẹyin aisan ranpẹ.

Lẹyin naa l’Ọgbẹni Rafiu Kazeem Ọpẹyẹmi, kagbako ijanba ọkọ, to si tibẹ jẹ Ọlọrun nipe lọjọ Abamẹta, Satide, ninu iṣẹlẹ ti awọn meji mi-in, Ọgbẹni Ṣẹgun Oni ati Ajadi Ọdunayọ, ti fara pa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lagbegbe Osu, nipinlẹ Ọṣun, l’Ọpẹyẹmi, to jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn rẹfiri lagbegbe Ọna Ara, nipinlẹ Ọyọ, ti kagbako ijanba oju popo ọhun nigba ti oun atawọn ẹgbẹ rẹ n pada bọ wa s’Ibadan lati Abuja, nibi ti wọn ti lọọ dari idije ere idaraya kan gẹgẹ bii rẹfiri ti gbogbo aye mọ wọn si.

Ẹgbẹ awọn oniroyin ere idaraya nilẹ yii, (Sports Writers’ Association of Nigeria (SWAN), ẹka tipinlẹ Ọyọ, ti kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn oloogbe naa.

Ninu atẹjade ibanikẹdun ti alaga ẹgbẹ ọhun, Ọgbẹni Niyi Alebioṣu ati Akọwe ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Adewale Tijani, fọwọ si ni wọn ti ṣàpèjúwe iku awọn atọkun ere idaraya naa gẹgẹ bii adanu nla fun ipinlẹ Ọyọ ati orileede Naijiria lapapọ.

Ẹgbẹ SWAN Ọyọ waa pe ẹgbẹ awọn rẹfiri (NRA) nija lati ma ṣe jẹ ki iku awọn eeyan yii ja sofo pẹlu fifi nnkan sọri wọn ni iranti ipa ti wọn ko fun idagbasoke ere bọọlu nipinlẹ Ọyọ.

 

Leave a Reply