Jọkẹ Amọri
Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ko figba kan wa lẹyin awọn to n pe fun ipinya Naijiria. Ṣugbọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ yii, lo tun waa bo kinni ọhun loju tan, aarẹ tẹlẹ naa sọ pe ohun yoowu ko ṣẹlẹ, Naijiria ko ni i tuka, yoo maa wa nikan ṣoṣo lọ ni.
Ilu Eko l’Ọbasanjọ ti sọrọ yii, lasiko to lọọ ba Ojiṣẹ Oluwa, Sunday Mbang, yọ ayọ ọjọọbi ọdun karundinlaaadọrun-un (85), ati ifilọlẹ iwe kan to sọ itan igbesi aye baba naa.
Nigba to n ṣalaye, Ọbasanjọ sọ pe awọn kan wa ti wọn jẹ ọta Naijiria, o ni wọn pọ, ṣugbọn wọn ko ni i ri kinni naa ṣe pe ki Naijiria tuka. O ni wọn yoo ṣubu ni.
Ọbasanjọ sọ pe bi Naijiria ba wa lodidi bo ṣe wa yii, o pe wa pupọ, nitori ohun ti a maa koju papọ gẹgẹ bii iran eniyan rọrun, o si tura ju ka tuka yẹlẹyẹlẹ lọ.
O loun gẹgẹ bii ẹnikan, iṣọkan orilẹ-ede yii loun yoo maa ṣiṣẹ fun. O ni labẹ bo ṣe wu ko ri, ati ohun yoowu ko ṣẹlẹ, Naijiria yii ko ni i pin, awọn to jẹ ọrẹ Naijiria ni yoo bori, awọn ọta rẹ yoo ṣubu ni.
Ẹ oo ranti pe awọn ajijagbara ti wọn n beere Orilẹ-ede Oduduwa ko duro, bẹẹ lawọn Ibo ti wọn n beere Biafra naa ko sinmi. Ṣugbọn Ọbasanjọ ni oun gẹgẹ bii ẹnikan ko ni i fara mọ ipinya, oun ko ni i ba awọn to fẹẹ tu Naijiria ka ṣe ni toun.