Ladọja wọ Makinde, Olubadan atawọn agba ijoye to fi jọba lọ si kootu

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọrọ oye ilu Ibadan ti waa di egbinrin ọtẹ bayii o, bi ọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru. Ọrọ oye ọba ti Olubadan Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ati ijọba ipinlẹ Ọyọ fi awọn oloye Ibadan jẹ laipẹ yii ti tun di wahala. Eyi ko sẹyin bi ọkan ninu awọn agba oye Ibadan, Ọtun Olubadan, Sẹnetọ Rashidi Ladọja ṣe gbe ọba naa lọ si kootu lori igbesẹ ọhun.

Lopin ọsẹ to kọja, iyẹn, lẹyin bii wakati meloo kan ti wọn gbe ọpa ṣẹ fun awọn ọba tuntun naa, eyi ti Ladọja ko si lara wọn, ni wọn fiwe ipẹjọ le wọn lọwọ.

Nigba to n fidi igbesẹ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ALAROYE, ọkan ninu awọn ọba tuntun naa,

Ọba Amidu Ajibade, to tun jẹ Ẹkẹrin Olubadan ilẹ Ibadan, fidi ẹ mulẹ pe, “wọn ti mu iwe ipẹjọ wa, ẹru kankan ko si ba mi, nitori mi o ṣe ohun to lodi sofin.

“Mi o kọja aaye mi, ko si sẹni ti wọn maa fi nnkan rere lọ ti ko ni i gba a, nitori ko sẹni ti oriire ko wu.”

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, l’Ọba Balogun ti i ṣe Olubadan ilẹ Ibadan sọ awọn agba ijoye rẹ di ọba alade.

Sẹnetọ Ladọja, ẹni to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ nikan ni ko gba ade ọba ninu awọn agba ijoye Olubadan naa nitori ko yọju sibi eto igbade ọhun rara.

Awọn agba ijoye naa ti wọn ṣẹṣẹ bọ sipo ọba ko ti i pari pọpọṣinṣin iwuye wọn ti iwe ẹjọ fi tẹ wọn lọwọ. Laipẹ yii ni gbogbo wọn yoo si maa wi tẹnu wọn ni kootu, nigba ti igbẹjọ ọhun ba bẹrẹ ni pẹrẹu.

Awọn ti yoo maa jẹjọ ni kootu ni Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Ọlakunlẹhin; Tajudeen Ajibọla (Ọtun Balogun); Lateef Adebisi Adebimpe (Osi Balogun), Eddy Oyewọle (Osi Olubadan)

Kọlawọle Adegbọla (Aṣipa Balogun), Abiọdun Kọla Daisi (Aṣipa Olubadan) Dada Isioye (Ẹkẹrin Balogun)

Awọn yooku ni Hamidu Ajibade (Ẹkẹrin Olubadan); Dada Isioye (Ẹkẹrin Balogun); Adebayọ Akande (Ẹkarun-un Olubadan); ati Abiọdun Dauda Azeez (Ẹkarun-un Balogun).

Leave a Reply