Monisọla Saka
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorilẹ-ede wa, EFCC, ti kede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, pe onile to ba file haaya fun awọn onigbaju-ẹ ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni yahoo yahoo n fi ẹwọn ọdun marundinlogun runmu ni o.
Ajọ yii fi ọrọ yii lede lori ikanni ẹrọ alatagba Insitagiraamu ati Tuita wọn, nibi ti wọn ti n ke si awọn araalu lati wa fun ipade ilu ti wọn yoo ṣe lori ikanni ẹrọ ayelujara ti wọn pe akọle ẹ ni “Lanlọọdu: Gbele kalẹ fawọn ọmọ yahoo yahoo, fi ẹwọn ọdun mẹẹẹdogun jura”.
Ninu fọnran fidio ti wọn sọ sori afẹfẹ ọhun ni awọn ajọ EFCC ti ni pataki ipade ori afẹfẹ ọhun ni lati tubọ fọrọwerọ, ki wọn si tun lo anfaani ọhun lati fi sun mọ awọn eniyan ilu si i.
Wọn ti ṣe ikilọ fawọn to n ya ni nile lati dẹkun a n gbele fawọn ti iṣẹ ọwọ wọn ko mọ, paapaa ju lọ awọn ọmọ yahoo yahoo, gẹgẹ bo ṣe jẹ pe awọn ti tubọ ṣan ṣokoto awọn le lati doju ija kọ awọn apanilẹkunjaye ẹda ọhun.
Ipade ori afẹfẹ yii waye lori ikanni Tuita (Twitter) wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.