Gbenga Amos, Abẹokuta
“Awọn adigunjale to n ṣọṣẹ nipinlẹ Ogun yii, Eko ni wọn ti n wa, wọn o si nipinlẹ Ogun nibi, ṣugbọn ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni wọn. Awọn afurasi tawọn ọlọpaa ti n wa tipẹ lọ pọ ninu wọn.”
Abiọdun, ogbologboo adigunjale kan lo fẹnu ara ẹ jẹwọ ọrọ yii fawọn oniroyin ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweeran, l’Abẹokuta, laarin ọsẹ yii.
Ireti ijọba ati araalu ni ki ẹni ti wọn ran lẹwọn lọọ kọgbọn, ki igbe aye le yipada si daadaa to ba jade, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun Mọruf Abiọdun yii ni tiẹ, oko ole mi-in lọwọ ti ba baale ile ẹni ogoji ọdun yii lẹyin to tẹwọn de, o ni ẹwọn ọdun meji toun kọkọ lọ ni wọn ti juwe ẹgbẹ adigunjale tuntun toun ṣẹṣẹ n ba ṣiṣẹẹbi yii foun.
O ṣalaye pe ọkada Bajaj kan loun ji gbe lalakọọkọ tile-ẹjọ fi ran oun lẹwọn oṣu meji ni ọdun mẹta sẹyin.
“Nigba ti mo n ṣẹwọn naa lọwọ, emi ati awọn ẹlẹwọn ẹlẹgbẹ mi la n sọrọ nipa ohun ta a maa ṣe ti kaluku ba pari ẹwọn rẹ. Ibẹ ni wọn ti fun mi ni nọmba ikọ adigunjale ti mo le dara pọ mọ, ti wọn si juwe bi mo ṣe maa ri wọn fun mi.
“Nigba ti wọn da mi silẹ lẹwọn, kia ni mo ti pe nọmba ti wọn fun mi, ni mo ba di ọmọ ẹgbẹ adigunjale tuntun yii, emi ni wọn fi ṣe dẹrẹba to n wa wọn.
“Kin n sọ tootọ, adigunjale ni mi, awa marun-un la wa ninu ikọ adigunjale wa, ṣugbọn emi nikan lọwọ ba. Ibọn ti wọn ba nile mi lo ṣakoba, emi dẹ kọ ni mo ni ibọn yẹn, ọkan ninu awọn mẹmba ikọ wa lo ni in, ilu Eko loun n gbe.
“Ọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, ni wọn mu mi, ko si ti i ju oṣu mẹfa lẹyin ti mo pari ẹwọn ti Bajaj ti mo ji gbe lọjọsi lọ.
“Tori ati jẹun ni mo ṣe n jale. Mo mọ ọpọ awọn adigunjale ati ikọ wọn ni ipinlẹ Ogun yii daadaa.
“Ireti mi ni kijọba ṣiju aanu wo mi, ki wọn dari ẹṣẹ ji mi.” Mọrufu lo sọ bẹẹ.