Lasiko tiyawo baale ile yii lọ fun odun Ileya lo gbe ale wale, niyẹn ba gun un pa

Monisọla Saka

Ọkunrin kan to ni iyan sile, to tun n da ọka laamu nita, ti pade iku ojiji latọwọ obinrin to n nawo le lori nita. Baale ile ti wọn n pe ni Ayinde Israel yii niyawo nile, bẹẹ ni Ọlọrun ti jogun ọmọ kan fun wọn, ṣugbọn ti obinrin to gbe wale lasiko tiyawo ẹ ti lọ sile ọdun ṣeku pa a.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ ofin gbe afurasi ti wọn pe orukọ rẹ ni Alice, latari bo ṣe gun ọkunrin ti wọn jọ n ṣe ifẹ ikọkọ pa niluu Itori, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi alaye ti obinrin kan ṣe loju opo ayelujara Instagram, irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, niṣẹlẹ buburu naa waye.

Wọn ni iyawo Israel, ati ọmọ ọdun kan to n tọ lọwọ ni wọn jọ lọ sile ọdun Ileya, aisi iyawo ẹ nile yii loun ri bii oore-ọfẹ lati tẹ ifẹ inu ẹ lọrun, nitori bẹẹ lo si ṣe gbe ale ẹ wa sile lati sun mọju.

Obinrin ọhun ṣalaye pe, “Oloogbe niyawo nile, amọ nitori pe iyawo lọọ ṣe ọdun Ileya lọdọ awọn ẹbi ọkọ pẹlu ọmọ wọn ni Israel ṣe gbe obinrin mi-in wa sinu ile wọn lọjọ tiyawo kuro nile gangan.

Wahala kan lo waye laarin oun ati obinrin naa tiyẹn fi gun un lọbẹ lọrun. Ọsibitu meji ọtọọtọ la gbe e lọ, ṣugbọn ẹlẹmii pada gba a”.

ALAROYE gbọ pe ileewosan kan ti wọn n pe ni Shodipọ, ni wọn kọkọ gbe e lọ, ṣugbọn awọn yẹn o tete da wọn lohun. Fun bii wakati mẹta, wọn ṣi wa nibẹ ti ọkunrin naa n japoro oju ibi ti ale ẹ ti gun un. Ni gbogbo igba ti wọn fi n duro yii, o ti padanu ẹjẹ gidi gan-an. Nigba ti wọn fi maa gbe e dele iwosan ti wọn ti pada gba a lati tọju rẹ, o ti dagbere faye”.

Wọn ni awọn agbofinro ti da Alice duro si teṣan ọlọpaa Ifọ, nipinlẹ Ogun, fun ifọrọwanilẹnuwo ati iwadii to yẹ.

Leave a Reply