Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Olumoyero Ayọmide Habeeblah, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, to jẹ ọmọ bibi ilu Ifọn-Ọṣun, lo ti n ka boroboro lakata awọn Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun bayii lori ẹsun ole jija.
Gẹgẹ bi Habeeblah ṣe jẹwọ fun ALAROYE, lasiko to wa lọgba ẹwọn ilu Ileṣa lori ẹsun ipaniyan ati jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun lo ṣalaabapade awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ ole bayii.
Lori ohun to gbe e dọgba ẹwọn nigba naa, ọkinrin afurasi yii ṣalaye pe lasiko ti oun jẹ akẹkọọ nileewe ẹkọṣẹ imọ ẹrọ, iyẹn Ọṣun Stete College of Technology (OSCOTECH), niluu Ẹsa-Oke, loun darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
O ni ija kan bẹ silẹ laarin ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ati Aiye nibẹ lọdun 2014, eeyan meji si ku, bayii ni ọwọ tẹ oun atawọn mẹta mi-in, lẹyin ti wọn pooyi kootu ni wọn dajọ lọdun 2017 pe ki wọn lọọ ṣẹwọn ọdun mọkanlelogun.
Lọgba ẹwọn yii lo ni oun ti ṣalaabapade Tayọ Ogunniran to jẹ ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ, ti awọn si jọ maa n sọrọ daadaa titi to (Tayọ) fi gba ominira ni tiẹ.
Habeeblah fi kun ọrọ rẹ pe lẹyin ti oun lo ọdun mẹsan-an lọgba ẹwọn ni adajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ kan lorileede yii sọ pe ki wọn tu oun silẹ lahaamọ, ti oun si gba ominira ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2021.
Ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, Habeeb ṣalaye siwaju pe oun lọ sibi igbeyawo abigbẹyin mama oun ni Iragbiji, nibẹ loun si ti ṣalaabapade Kunle ti wọn jọ wa lọgba ẹwọn nigba naa, to si fun un ni nọmba Tayọ.
O ni nigba toun ṣalaye gbogbo bi nnkan ko ṣe lọ deede fun Tayọ lori foonu niyẹn sọ foun pe ohun gbogbo yoo pada bọ sipo ti oun ba le maa ri ọkada ji, nitori oun ni ẹni to maa n ra a ni Ogbomọṣọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe latigba naa loun ti bẹrẹ iṣẹ jiji ọkada pẹlu iranlọwọ ọmọkunrin Hausa kan torukọ rẹ n jẹ Usman, to n gbe niluu Ifọn. O ni o kere tan, awọn ti ji to ọkada mẹfa laarin oṣu kẹta sigba ti ọwọ tẹ awọn.
Yatọ si ọkada, Habeeblah jẹwọ pe oun tun ti ji to foonu mẹẹẹdọgbọn, ti oun si tun maa n ja baagi gba lẹẹkọọkan ti anfaani rẹ ba yọ niluu Oṣogbo.
O ni Usman ni yoo wa ibi ti manṣinni wa, to ba si ti sọ fun oun loun yoo pe Tayọ pe ko maa bọ l’Ọṣun, ti awọn ba si ti yọ irin oju windo lẹnikan yoo wọle lọọ ṣilẹkun, tawọn yoo si gbe ọkada sita.
Latigba ti wọn ti n ṣiṣẹ yii, o ni oko (farmland) ni ohun fi gbogbo owo ti oun ri nibẹ ra, ti oun si gba awọn eeyan lati maa ba oun ṣiṣẹ nibẹ.
O ni ọkan lara awọn mọlẹbi Usman lo ra ọkada niluu Ifọn, ti iyẹn si pe oun pe ki awọn waa ji i gbe, o ni lẹyin ti awọn ji manṣinni naa, ti awọn gbe e de agbegbe Irẹsaadu, nipinlẹ Ọyọ, lọwọ awọn Amọtẹkun tẹ awọn.
Ninu ọrọ Alakooso Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Comreedi Amitolu Shittu, o gboṣuba fawọn Amọtẹkun ipinlẹ Ọyọ fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe, o ni ipinlẹ mejeeji ti di ibi aiwọ fun awọn ọdaran bayii.
Amitolu fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe ko sewu kankan fun wọn lasiko ọdun Keresi ati ọdun tuntun to n bọ lọna, nitori eto aabo to peye wa nilẹ fun wọn.