Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Nitori eto aabo ẹmi ati dukia awọn araalu, ijọba ipinlẹ Ondo, labẹ iṣakoso Arakunrin Rotimi Akeredolu, ti bẹrẹ eto kiko awọn onibaara atawọn alarun ọpọlọ kuro laarin ilu.
Akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ awọn obinrin, Abilekọ Folukẹ Tunde-Daramọla, to ṣe agbatẹru eto naa ni o ti di nnkan eewọ fawọn onibaara tabi awọn to larun ọpọlọ lati maa rin bo ṣe wu wọn lawọn ilu nla nla to wa nipinlẹ Ondo lati asiko yii lọ.
Eto yii lo ni awọn ti bẹrẹ niluu Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo lọsẹ to pari yii, ti ko si ni i pẹẹ tan de awọn ilu yooku laipẹ rara.
O ni ijọba gbe igbesẹ yii lati mu adinku ba ọkan-o-jọkan iwa ọdaran to n waye lemọlemọ, ati kawọn ilu wọnyi le lẹwa, ki wọn si dun-un wo si i.
Abilekọ Daramọla ni ko si aniani pe inu ijọba ko dun rara si bawọn alagbe, ọlọdẹ-ori atawọn to n ta wosiwosi ojal loju popo ṣe n pọ si i laarin ilu, nitori ewu to le tidi rẹ yọ.