Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọgọọrọ awọn agbẹjọro ni wọn tu yaayaa jade niluu Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, lati fẹhonu han ta ko bi ijọba ṣe kuna lati dahun ohun tawọn oṣiṣẹ kootu n beere fun lati bii ọsẹ mẹta ti wọn ti bẹrẹ iyansẹlodi.
Awọn lọọya ọhun pẹlu oriṣiiriṣii patako ti wọn gbe lọwọ ni wọn kọkọ pejọ siwaju ọgba ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ondo to wa lagbegbe Oke-Ẹda, nibi ti wọn ti to lọwọọwọ lọ si ọfiisi gomina to wa ninu Alagbaka, niluu Akurẹ, lati fẹdun ọkan wọn han si Gomina Rotimi Akeredolu.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn agbẹjọro nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, Ọgbẹni Rotimi Ọlọrunfẹmi, akẹgbẹ rẹ lati ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, Amofin Thompson Akinyẹmi ati Orimisan Okorimisa lati ijọba ibilẹ Okitipupa ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu akọroyin ALAROYE ni gbogbo ọna lawọn fi ṣatilẹyin fun iyansẹlodi ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu to n lọ lọwọ ti ijọba yoo fi ṣohun to tọ fun wọn.
Wọn ni o ti to akoko to yẹ ki ileesẹ eto idajọ wa lominira ara wọn ninu ninu eto inawo, ki wọn le lanfaani ati ṣiṣẹ wọn bo ti tọ ati bo ti yẹ labẹ ofin lai bẹru ẹnikẹni.
Wọn ni ẹbẹ lawọn n bẹ Akeredolu lati bọwọ fun abala ikọkanlelọgọfa (121), ila kẹta ninu iwe ofin orilẹ-ede yii.