Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Motunrayọ Balogun, la gbọ pe o gbiyanju ati gbẹmi ara rẹ pẹlu bo ṣe gboogun jẹ nitori pe ọrẹkunrin rẹ ja a silẹ lojiji.
Ọmọbinrin to n gbe ninu Ẹsiteeti Ijapọ, niluu Akurẹ, naa la gbọ pe ọrẹkunrin re deedee jawee ‘mi o ṣe mọ’ fun lai sọ idi kan pato to fi gbe igbesẹ naa. Eyi la gbọ pe o ba ọmọbinrin naa ninu jẹ to fi pinnu lati gbẹmi ara ẹ.
ALAROYE gbọ pe iya Motunrayọ lo ba ọmọ rẹ nilẹẹlẹ ninu yara ile ti wọn n gbe, nibi to ti n pọkaka iku, pẹlu igo majele to ṣẹṣẹ gbe jẹ lọwọ rẹ.
Kia ni obinrin yii sare pe awọn araadugbo, ti wọn si jọ gbe e lọ si ọsibitu kan to wa nitosi, nibi tawọn dokita ti ṣiṣẹ takuntakun ki wọn too ri i ji pada saye.
Ọrẹ timọ timọ Motunrayọ ta a forukọ bo laṣiiri ṣalaye fun akọroyin wa pe kayeefi patapata niṣẹlẹ ọhun ṣi n jọ loju oun nitori ko ye oun rara idi ti ọrẹ oun fi pinnu lati pa ara rẹ nitori ọkunrin.
O juwe Motunrayọ bii arẹwa obinrin, ẹni tawọn ọkunrin yoo fẹran ati fẹ laya latari ọyaya ati akikanju rẹ nibi iṣẹ.
Ọmọbinrin naa ni ko si igba kan ti ọrẹkunrin rẹ yii maa n fi ọrẹ oun lọkan balẹ pẹlu gbogbo bo ṣe n gbiyanju ati tẹ ẹ lọrun to, o ni niṣe lo maa n ṣọ ọ kiri ibikibi to ba lọ.
Ọrẹ Motunrayọ yii ni o ṣee ṣe ko jẹ pe ṣe ni ọmọkunrin naa mọ-ọn-mọ kọju Motunrayọ si oorun alẹ nigba to ri i pe ọdun Keresimesi ti ku si dẹdẹ, gẹgẹ bii iwa ati iṣe awọn ọkunrin kan ti wọn maa n ja ọrẹbinrin wọn si ọlọpọn nigba ọdun, nitori aifẹẹ ṣe ojuṣe to yẹ lori wọn.
Ara Motunrayọ la gbọ pe o ti n ya diẹdiẹ nileewosan to ti n gba itọju.