Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari rogbodiyan to bẹ silẹ niluu Ikarẹ Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, lalẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii, ijọba ipinlẹ Ondo ti kede konile-gbele oni wakati mẹrinlelogun kaakiri ilu ọhun.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Richard Ọlatunde, fi sita, o ni ipinnu yii waye lẹyin ipade ti Arakunrin Rotimi Akeredolu ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, pẹlu igbimọ to n ri sọrọ eto aabo nipinlẹ Ondo.
O ni Gomina Akeredolu ti kọkọ ṣe ipade pẹlu Olukarẹ tilu Ikarẹ Akoko, Ọba Akadiri Momoh, ati Ọba Adeleke Adegbitẹ to jẹ Ọwa-Ale Iyọmẹta, to si rọ wọn lati ba awọn eeyan wọn sọrọ, ki alaafia le tete jọba lagbegbe naa.
Kikuna awọn ọba alaye mejeeji lati gbe igbesẹ to yẹ pẹlu bi rogbodiyan ọhun ṣi ṣe n tẹsiwaju lẹyin ọjọ meji ti wọn ti wa lẹnu rẹ lo ni o ṣokùnfà igbesẹ kikede konile gbele naa.
Ọlatunde ni ko gbọdọ si irinkiri ọkọ tabi ti eeyan mọ niluu Ikarẹ lati akoko yii lọ titi di igba ti wọn yoo tun ṣe ikede mi-in lori eleyii.
O fi kun un pe ijọba ti fun awọn ẹṣọ alaabo laṣẹ lati ri i daju pe ofin naa fidi mulẹ, bakan naa lo ni ẹkunrẹrẹ ìwádìí ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokùnfà rogbodiyan ọhun.
Aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, kan naa ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Oyeyẹmi Oyediran, ṣe abẹwo siluu Ikarẹ, nibi to ti ṣepade alaafia pẹlu Olukarẹ, Ọba Akadiri Momoh, atawọn araalu mi-in ti ọrọ kan.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, fidi rẹ mulẹ fun akọroyin wa pe kọmiṣanna fi asiko abẹwo ọhun rọ Olukarẹ lati beere fun iranlọwọ ijọba atawọn to mọ itan ilẹ daadaa, ki wọn le ba wọn yanju ọrọ aala ilẹ to n fa gbọn-mi-si-i, omi-o to-o ni gbogbo igba lagbegbe Ikarẹ.
Ọga ọlọpaa ọhun tun rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan lati fọwọ wọnu, ki wọn si yago fun ṣiṣe idajọ lọwọ ara wọn, o ni ẹnikẹni to ba n binu lẹtọọ lati lọọ fẹjọ sun awọn agbofinro tabi ko gba ile-ẹjọ lọ.
Oyeyẹmi tun ba awọn ẹbi to padanu eeyan wọn atawọn to padanu dukia sinu rogbodiyan naa kẹdun.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wahala deedee bẹ silẹ lasiko tawọn ọdọ kan lagbegbe Ọkọja, niluu Ikarẹ Akoko, n ṣayẹyẹ kanifa, nibi ti wọn ti n ṣe ajọyọ yii lawọn ọdọ mi-in lati Ọkọja kan naa ti yọ si wọn lojiji, tọrọ si di pẹẹ-n-tuka.
Lati igba naa si ni iro ibọn ti n dun lakọlakọ kaakiri ilu Ikarẹ, gbogbo ṣọọbu itaja ni wọn ti pa, ti ko sẹni to too yọju lati na Ọja-ọba, eyi ti wọn n na lojoojumọ niluu ọhun.
Ọpọ awọn ọkọ atawọn arinrin-ajo to yẹ ki wọn gba ilu Ikarẹ kọja lọ si agbegbe Oke-Ọya, ni wọn ti wa ọna mi-in igba, iyẹn ọna marosẹ Akungba si Ọka Akoko.