Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ni itẹsiwaju pẹlu ileri ẹ lati maa gbe fọto ati orukọ ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun ifipabanillopọ nipinlẹ Ekiti jade, ileeṣẹ eto idajọ ti kede ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Lateef Oluwaṣeun.
Lateef to n gbe laduugbo Anaye, niluu Aramọkọ-Ekiti, lawọn ọlọpaa sọ pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla kan lo pọ, bẹẹ ni wọn ko oriṣiiriṣii ẹri kalẹ nile-ẹjọ lati fidi ẹsun naa mulẹ.
Lasiko idajọ ni wọn dajọ ẹwọn gbere fun Lateef, eyi lo si mu ileeṣẹ eto idajọ kede orukọ ẹ, bẹẹ ni fọto ẹ yoo wa laduugbo ati ijọba ibilẹ ẹ lati jẹ ẹkọ fawọn ọbayejẹ mi-in.
Tẹ o ba gbagbe, alufaa ijọ Anglican tẹlẹ kan, Gabriel Aṣatẹru, lo kọkọ ṣide ikede yii lẹyin to fipa ba ọmọ ọdun meje kan lo pọ niluu Ifiṣin-Ekiti, eyi to jẹ ki kootu sọ ọ sẹwọn ọdun marun-un.
Ẹni keji to ko sọwọ ijọba ni Ajibade Ọlaoluwa David, ẹni to fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla kan lo pọ niluu Aiyede-Ekiti tadajọ si sọ ọ sẹwọn ọdun mẹwaa.
Lẹyin naa lọwọ tẹ Basiru Adeyanju ati Abiọdun Oluṣọla.
Adeyanju to n gbe laduugbo Irọna, niluu Ado-Ekiti, lo fipa ba ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan laṣepọ, ẹwọn ọdun mẹrinla ni wọn si sọ ọ si.
Ni ti Oluṣọla, ilu Ijero-Ekiti loun ti fipa ba iya agbalagba ẹni ọdun mọkanlelọgọta kan lo pọ, eyi to fi gba idajọ ẹwọn ọdun mẹwaa gbako.
Bakan naa ni Ajewọle Dada Filani huwa tiẹ niluu Ikẹrẹ-Ekiti pẹlu bo ṣe fipa ba ọmọ ọdun mẹtalelogun kan laṣepọ, ẹwọn gbere nijiya rẹ si ja si.