Lati din bawọn araalu ṣe n mu un ku, ijọba fẹẹ fi kun owo-ori siga

Adewale Adeoye

Bi ọrọ to n jade lẹnu awọn alaṣẹ ijọba apapọ ilẹ yii ba jẹ ootọ,  a jẹ pe  afikun yoo ba owo-ori (Tax) tawọn ileeṣẹ to n ṣe siga nilẹ yii yoo maa san sapo ijọba.

Wọn ni afikun owo ori naa yoo gbe pẹẹli soke si i lati ida ọgbọn si aadọta (30% -50% ). Idi pataki ti wọn ni awọn ṣẹ fẹẹ ṣẹ afikun naa ni ko le din bawọn araalu ṣẹ n mu siga naa ku nigba gbogbo, eyi ti wọn sọ pe o n ṣe akoba nla fun ilera ọpọ awọn eeyan lawujọ wa bayii.

Ninu ọrọ ọkan pataki lara awọn ọga agba lẹka ileeṣẹ to n mojuto ọrọ siga nilẹ yii labẹ ileeṣẹ eto ilera lorile-ede yii, niluu Abuja, Dọkita Mangai Malau, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo sọrọ ọhun di mimọ niluu Abuja lọhun.

O ni awọn gbọdọ ṣe afikun owo-ori siga ko le rọrun gidi fawọn alaṣẹ ijọba ilẹ yii lati le gbogun ti mimu siga.

Dọkita Mangai Malau ni, ‘ Bi ijọba apapọ ilẹ wa ba fẹẹ gbogun ti, tabi din bawọn kan ṣe n mu siga naa ku bayii, wọn nilo owo gidi gan-an lati ṣe bẹẹ, lara ọna kan gboogi ta a si fi le ri awọn owo ọhun ni pe ka ṣe afikun sowo-ori (Tax) tawọn ileeṣẹ to n ṣe siga nilẹ yii n san lọdọọdun fun ijọba apapọ.

‘Ijọba fẹẹ gbe owo ohun soke lati ida ọgbọn si aadọta (30% -50% )  bayii. Eyi gan-an lo wa ni ibamu ati ilana ajọ eleto ilera agbaye ti wọn n pe ni (WHO). Wọn ni orile-ede kọọkan ni yoo wa ọna ti yoo gba lati fi wa owo ti yoo maa loo lati maa fi ṣepolongo fawọn araalu rẹ nipa ewu to wa ninu siga mimu. Wọn ni ipalara ti ki i ṣe kekere lo n mu ba awọn to n mu un.

Leave a Reply