Lati Eko ni Celestine ti ko ayederu Naira tuntun lọ s’Ekiti, awọn Amọtẹkun ti mu un

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Owo Naira ti ko ti i pẹ rara ti wọn ṣe e jade ni awọn kọlọransi ẹda kan ti n ṣe ayederu rẹ, ti wọn si n lo anfaani pe owo ọhun wọn nita lati na an fun awọn araalu ti ko ba fura.

Iru rẹ ni ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Celestine Nwoha ṣe, lati ilu Eko lo ti ko ọpọlọpọ ayederu owo Naira tuntun lọ si Ekiti lati maa na an lọhun-un, ṣugbọn ọwo palaba rẹ ṣegi pẹlu bo ṣe ko si panpẹ ẹṣọ Amọtẹkun, ni wọn ba fọwọ ofin mu ọkunrin ẹni ogoji ọdun ọhun.

Nigba ti wọn n fibeere po o nifun pọ, Celestine ni ọmọ bii ilu Ihiala, nipinlẹ Anambra, loun. O jẹwọ pe oun ti na ninu owo naa ni ọja nla kan to wa ni Omuo-Ekiti, bakan naa loun ti na ayederu owo ọhun fun awọn to n lo maṣinni kekere lati fi sanwo, iyẹn awọn oni POS.

O ni oniṣowo loun, lati ilu Eko loun si ti maa n lọ si Isanlu, nipinlẹ Kogi, lati ra obi ati orogbo. Nigba to n ṣalaye bo ṣe ko si ọwọ awọn Amọtẹkun, ọmọkunrin yii sọ pe ilu Eko loun ti n bọ lọjọ naa, ṣugbọn oun duro ni Omuo-Ekiti, lasiko ti oun fẹẹ na ayederu owo naa fawọn oni POS ni aṣiri tu, ibẹ ni wọn si ti ranṣẹ si awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti wọn fi mu oun pẹlu ayederu owo Naira to wa lọwọ oun naa.

Ninu awijare rẹ, Celestine ni oun ko mọ pe ayederu ni owo naa, o ni ọwọ onibaara oun kan loun ti gba a niluu Eko.

Nigba ti wọn n ṣe afihan afurasi yii ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Ado-Ekiti, Ọga ẹṣọ Amọtẹkun naa, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe awọn eeyan ilu Omuo-Ekiti ti wọn n ṣiṣẹ POS ni wọn ta awọn ẹṣọ Amọtẹkun lolobo nipa igbesẹ ọkunrin naa.

O ṣalaye pe ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni awọn ẹṣọ Amọtẹkun lọ sibẹ, wọn si ba ọpọlọpọ ayederu owo lọwọ ọdaran ọhun.

Kọmọlafẹ ṣalaye pe ọmọkunrin naa ti wa lakata awọn, awọn yoo si taari rẹ si awọn ọlọpaa ni kete tiwadii ba pari lori ọrọ naa.

O waa kilọ fawọn eeyan awujọ lati yẹra fun awọn onijibiti ti wọn yoo maa lo anfaani owo to wọn nigboro lati gbe ayederu owo waa ba wọn.

Leave a Reply