Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ekiti, ti tẹ eeyan marun-un ti wọn jẹ ọmọ bibi Ikẹrẹ-Ekiti, ti wọn pe ara wọn ni oniṣegun ibilẹ, ṣugbọn to jẹ ogbologboo onijibiti ni.
Awọn ọdaran naa ti wọn pe orukọ ẹgbẹ wọn ni ‘Awo Jinginni’, ni wọn maa n lu awọn araalu ni jibiti, nipa pipe ara wọn ni babalawo.
Nigba to n ṣe afihan wọn ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Ado-Ekiti, ọga awọn Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe awọn ọdaran ọhun, Johnson Oluṣọla, ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44), Olufẹmi Sunday, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52), Aloba Ojo, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), Deji Ajayi, ẹni ọdun mejilelogoji (42), ati Dayọ Emmanuel, ẹni ogoji ọdun (40) fi ọgbọn jibiti gba owo to to miliọnu meji aabọ Naira lọwọ Udani James, ọkunrin agbẹ to n gbe ni ilu Abẹokuta.
Ọkunrin naa ṣalaye pe adugbo Odo-Ọja, n’Ikẹrẹ-Ekiti, tawọn ọdaran naa fi ṣe ibuba wọn ni wọn ti lọọ mu wọn.
Kọmọlafẹ sọ pe ọga awọn Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ogun, lo tẹ oun laago pe awọn onijibiti kan ni Ikẹrẹ-Ekiti, ti lu ẹnikan to n gbe ilu Abẹokuta ni ni jibiti, ti wọn ti gba owo to to miliọnu meji aabọ Naira lọwọ rẹ, ti wọn si tun n dunkooko mọ ọn pe awọn yoo gba ẹmi rẹ.
Ọga awọn Amọtẹkun yii sọ pe ni kete ti oun gbọ loun atawọn ọmọ ogun oun gbera lọ si ibuba wọn ni Ikẹrẹ-Ekiti, tawọn si ko diẹ lara oun eelo ti wọn n lo lati fi tan awọn eeyan jẹ.
Nigba to n sọ ti ẹnu rẹ, ọkunrin ẹni ogoji ọdun ti wọn gba owo lọwọ rẹ, Udani James, sọ pe agbẹ ni oun, ipinlẹ Benue loun ti wa, ṣugbọn Abeokuta loun n gbe.
O sọ pe ọkan lara awọn ọdaran naa lo sadeede pe oun lori ẹrọ ilewọ, to si bẹrẹ si i ṣe adura fun oun ni ilana Onigbagbọ.
O ṣalaye pe lẹyin ọpọlọpọ ọjọ to ti gba owo lọwọ oun loun sọ fun un pe oun ko nifẹẹ si gbogbo ohun to sọ pe ki oun ṣe, ni wọn ba bẹrẹ si i dunkooko mọ oun pe awọn yoo gba ẹmi oun ati awọn mọlẹbi oun ti oun ko ba fi owo ranṣẹ si awọn mọ.
O sọ pe eyi gan-an lo fa a ti oun fi lọọ fi ọrọ naa to awọn Amọtẹkun leti nipinlẹ Ogun, ki wọn too mu wọn nipinlẹ Ekiti.