Ademọla Adejare
Loootọ agbalagba oloṣelu ni Ahmed Bọla Tinubu, ṣugbọn bi eeyan ba sọ fun un pe ọrọ ibo aarẹ ọdun 2023 yoo ko o lọkan soke bi nnkan ṣe n lọ yii, yoo sọ pe ki onitọhun lọọ jokoo jẹẹ ni. Ṣebi loju tirẹ, ohun gbogbo lo ti pari, ko si si ẹni ti i ba yimiyimi du imi, ko sẹni to le ba oun Tinubu du ipo aarẹ naa rara, oun ni ẹgbẹ APC yoo fa kalẹ, bi ẹgbẹ APC ba si ti fa oun kalẹ, ko si ki oun ma wọle rara. Ero rẹ ni pe APC yoo fa oun kalẹ, nitori awọn adehun kan ti wa laarin oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari, adehun naa si ni pe bi awọn ara ilẹ Hausa ba ti jẹ tan, awọn ara Guusu orilẹ-ede yii ni yoo kan, ko si si Guusu kan nibi kan ju ilẹ Yoruba lọ. Tinubu ti ro pe bo ba ti da bẹẹ, ko sẹni kan ti yoo jade lati apa ibi yii ti yoo ni oun fẹẹ ba oun du ohunkohun, ki i tilẹ i ṣe ninu APC, nigba to jẹ oun ni aṣaaju gbogbo wọn. Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ o.
Ọrọ ko ri bẹẹ, nitori ọpọlọpọ awọn ara ilẹ Hausa ni wọn n fojoojumọ dide, iyẹn awọn oloṣelu wọn, ati awọn ti ki i ṣe oloṣelu paapaa, ti wọn n pe “ko si sóónì!”, iyẹn ni pe ko si jẹ ki n jẹ kan ninu oṣelu asiko yii, ẹni to ba dara ju ni awọn ọmọ Naijiria yoo mu. Wọn ni bo jẹ Hausa ni, bo jẹ Ibo ni, bo si jẹ Yoruba, ki kaluku jade lati fi ara rẹ han, ko si fa ara rẹ siwaju bii ẹni to le du ipo aarẹ, ki i ṣe ki awọn kan jokoo sibi kan, ki wọn ni ki ẹya mi-in ma ba awọn du ipo naa ju awọn nikan lọ. Eyi yatọ si adehun ati ohun ti Tinubu ti ro, ko si ronu pe iru awọn nnkan bayii le ṣẹlẹ tori adehun ọdun 2014, nigba ti wọn n lakaka lati da ẹgbẹ APC silẹ. Awọn ti wọn mọ nipa adehun naa sọ pe laarin Buhari ati Tinubu ni adehun naa kọkọ wa, igba ti awọn kan si gbọ ti wọn ko fẹẹ gba, Tinubu halẹ pe oun yoo ko APC toun kuro ninu ajọṣe naa, ni wọn ba n bẹ ẹ, ti wọn si n sọ pe awọn yoo ṣe ohun to ba fẹ.
Ọjọ ti waa pe, asiko ti Tinubu si ro pe oun yoo ko ire ree, asiko naa ni awọn eeyan waa jade lati ilẹ Hausa pe yoo ṣoro fun un lati ṣe. Awọn kan ti n fẹnu sọrọ naa tẹlẹ, ṣugbọn ọkunrin kan lo kuku bẹ ẹ lọsẹ to kọja, to ni oun n jade bayii, oun si n fẹnu ara oun sọ fun gbogbo eeyan pe oun yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC lọdun 2023. Ahmed Sanni Yerima lorukọ ọkunrin yii, ọkunrin to da Sharia silẹ ni ipinlẹ Zamfara lọjọsi ni. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu ANPP ni tẹlẹ, o si ti ṣe gomina ipinlẹ Zamfara yii fun ọdun mẹjọ, lati ọdun 1999 titi di 2007, lẹyin naa lo di sẹnetọ lati ọdun 2007 titi di ọdun 2019 to kọja yii, iyẹn ni pe o tun ṣe sẹnetọ naa fun ọdun mẹjọ, fun ọdun mẹrindinlogun bayii, ọkunrin naa ko ṣe iṣẹ mi-in ju iṣẹ oloṣelu ati iṣẹ ijọba lọ. Ọkan ninu awọn ti wọn jọ da APC silẹ ni, oun naa si mọ awọn adehun ti wọn ṣe ki wọn too da ẹgbẹ naa silẹ.
Ṣugbọn ni ibẹrẹ ọdun yii, iyẹn ni ọjọ kejila, oṣu ki-in-ni, ọdun 2020 ta a wa yii, Ahmad Sanni Yerima yii kede ni ilu Bauchi pe oun yoo du ipo aarẹ ni 2023, pe Yẹkinni kan ko le yẹ ẹ, nitori ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri Naijiria ni wọn n pe oun, ti wọn si n ni ki oun jade lati waa du ipo aarẹ, nitori oun lawọn fẹ ni ipo naa lati ọdun 2023 lọ. Ni asiko ti Yerima jade yii, to si sọ ọrọ naa ni gbangba, ti gbogbo awọn iwe iroyin ati ẹrọ ayelujara si gbe e, ko si ẹlomi-in to tun kede bẹẹ, ko si si ẹni to tun sọ pe oun yoo du ipo aarẹ ninu awọn oloṣelu APC gbogbo. Koda, Aṣiwaju Tinubu paapaa ko sọrọ to jẹ mọ bẹẹ, ohun to n wi ni pe asiko ko ti i to, ki awọn eeyan jẹ ki Buhari ṣejọba rẹ, ki ẹnikẹni ma ṣe sọrọ nipa ẹni ti yoo ṣejọba ni ọdun 2023, o si ṣekilọ pe oun ko sọ fẹnikẹni lati ṣe kampeeni, tabi sọrọ ipo aarẹ 2023 lorukọ oun.
Eyi ni ọrọ naa ko ṣe ya ọpọ eeyan lẹnu ni ọsẹ to kọja nigba ti Yerima jade sita wayi, to ni eto gbogbo ti pari, oun si ti bẹrẹ eto ipolongo toun lati du ipo aarẹ ni 2023, o ni bi oun ti ṣe sọ tẹlẹ, asiko to foun wayi, ko si ohun ti yoo si da oun duro. Nigba naa lawọn eeyan sọ ọ kan an loju pe ṣe ko gbọ pe wọn ti pin kinni naa si apa Guusu ilẹ Naijiria ni, pe nigba ti awọn ara Ariwa ti fi ọdun mẹjọ ṣejọba lorukọ Buhari, ko si ohun to tun kan wọn kan ijọba Naijiria fun ọdun mẹjọ mi-in, eeyan mi-in lati Guusu Naijiria lo gbọdọ ṣe e. Esi ti Yẹrima fun wọn ni pe ko sohun to jọ adehun bẹẹ, ati pe bi adehun bẹẹ ba wa laarin awọn kan, iru adehun bẹẹ ko le gbeṣẹ, nitori ko ba ofin Naijiria mu, ofin ko sọ pe ki a faaye gba jẹ-ki-n-jẹ, ẹni to ba kun oju oṣuwọn gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ ni yoo jade, ko si si ohun to le di ọmọ Naijiria lọwọ lati dibo fun un.
Ko kuku tilẹ yọ ọrọ naa sọ, o pe awọn oniroyin jade ni, o ni ki gbogbo wọn waa gbọ ikede ti oun fẹẹ ṣe, ikede naa si ni pe oun yoo du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023. Yerima ni ẹni to ba mọ itan oun yoo mọ pe ki i ṣe pe oun ṣẹṣẹ n ro o, o ti pẹ ti kinni naa ti wa lọkan oun, ati pe Buhari yii loun gbọdọ ṣejọba lẹyin ẹ, bo ba ti n gbejọba silẹ bayii, oun gan-an lẹni to gbọdọ tun bọ sibẹ lati ṣe e. Oun ni ohun ti yoo ṣe ri bẹẹ ni pe ninu ẹgbẹ kan naa ti awọn jọ n ṣe ni 2006 si 2007, oun Yerima kede faye pe oun yoo du ipo aarẹ, ṣugbọn nigba ti Buhari de, awọn agbaagba ẹgbẹ ati Buhari funra ẹ ba oun sọrọ, wọn si ni ki oun sọkalẹ, ki oun fi ipo naa silẹ fun un. O ni bi oun ṣe fi ipo silẹ fun Buhari ree to fi du ipo aarẹ ni 2007, bo tilẹ jẹ pe ko wọle nigba naa. O ni nigba ti ọrọ APC yii si tun ṣẹlẹ, oun tẹle ẹgbẹ oun lọ, oun si tun faaye silẹ fun Buhari.
Yatọ si Yẹrima to jade yii, ọpọ awọn oloṣelu ilẹ Hausa ni wọn n tẹnumọ ọn pe awọn ko mọ nipa adehun ti wọn n wi yii, ati pe ki ẹnikẹni ma fi adehun kan ti ko si lakọsilẹ kan tan awọn jẹ. Ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu ti sọrọ, bẹẹ ni ẹgbẹ ọdọ lati ilẹ Hausa, ohun ti wọn si n sọ ni pe ko yẹ ki ijọba kuro lapa ariwa, wọn ni asiko ko ti i to to yẹ ki ijọba bọ si ọdọ awọn ara Guusu, boya nilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo. Njẹ kin ni idi eyi, wọn ni ninu ogun ọdun o le ti wọn ti bẹrẹ ijọba dẹmọkiresi pada nilẹ yii, ọdun mẹrinla lawọn ara Guusu yii ti lo, bẹẹ ti awọn ara Ariwa yoo ṣẹṣẹ di ọdun mẹwaa ni ọdun 2023 ni. Wọn ni Ọbasanjọ lo ọdun mẹjọ, Jonathan lo ọdun mẹfa, ti Buhari yoo si ṣẹṣẹ pe ọdun mẹjọ ni ọdun 2023 ni, bi awọn ba si ro ọdun meji pere ti Yar’Adua lo mọ ọn, yoo di ọdun mẹwaa ti awọn ara ilẹ Hausa ṣi fi ṣejọba.
Awọn ọrọ nla nla yii lo jẹ ki Tinubu bẹrẹ si i fura, to si n ye e diẹdiẹ pe ohun ti oun ti n fẹẹ maa kọrin “wẹrẹ-lo-ba-mi-ṣe-e” le lori, ọrọ naa jọ pe yoo le ju bẹẹ lọ. Loootọ loun ti rin kiri ilẹ Hausa, to si n fun awọn ọba ati awọn eeyan pataki ni agbegbe naa ni ẹbun loriṣiiriṣii, ṣugbọn ọrọ naa n ye e wayi pe awọn oloṣelu adugbo naa ko ti i fi gbogbo ara wa lẹyin oun, nitori bi wọn ba fẹ ki oun du ipo aarẹ yii loootọ, wọn ko ni i maa yọ foroforo lọtun-un losi, ki wọn maa pariwo pe awọn naa fẹẹ du ipo aarẹ. Bi a ti n wi yi, Tinubu ti rin de Kano, o de Borno, o si n jẹ ki wọn mọ pe bi ijọba ba bọ sọwọ oun, oun ko jẹ fiya kan bayii jẹ wọn. Gbogbo awọn to n lọọ ba, atawọn to n ran awọn eeyan si, ni wọn n sọ pe ko sewu lọrọ rẹ, ṣugbọn oun naa ti ri i bayii pe ewu n bẹ, nitori ọwọ tawọn oloṣelu ati ajijagbara adugbo naa n gbe ko daa rara.
Ṣugbọn ewu to n wa lati ilẹ Hausa wọnyi ko mu ibẹru gidi ba Tinubu to eyi to n wa lati ẹkule ẹ nilẹ Yoruba nibi lọ. Ọrọ oun ati ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ rẹ ni, gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi. Ere ni Tinubu pe e, koda, ere lawọn eeyan pe e tẹlẹ, ṣugbọn bi ọrọ ti ri yii, oun naa ti mọ pe kinni naa ki i ṣe ere mọ o, o si ṣee ṣe ko ma jẹ awọn oloṣelu ilẹ Hausa ni wọn yoo ko wahala ba a, ko jẹ Kayọde Fayẹmi yii ni. Nigba ti ọrọ yii kọkọ n ja ran-in ran-in nilẹ, leyii ti awọn agba Ekiti ti sọrọ nigba kan pe asiko awọn Ekiti niyi lati fa aarẹ Naijiria kalẹ, awọn eeyan ko kọkọ ka kinni naa si, paapaa nigba ti Fayẹmi funra ẹ sọ pe oun o ṣetan lati gba ipo lọwọ Buhari. Ṣugbọn ọrọ naa tun ru jade ni bii oṣu meji sẹyin, nigba ti Fayẹmi lọ si Kaduna, ti Gomina El-Rufai si sọ ni gbangba nibẹ pe ko ni i pẹ ko ni i jinna ti aye yoo fi mọ ohun ti awọn ati Fayẹmi jọ n se.
Nibi ayẹyẹ to lọ ni Kaduna yii, Sultan ti i ṣe olori awọn ọba ilẹ Hausa sọ nibẹ pe awọn ara ilẹ Hausa ti gba Fayẹmi gẹgẹ bii ọmọ awọn, nitori ọmọ olori oloṣelu awọn tẹlẹ, Sardauna Ṣokoto, Ahmadu Bello, ni. Itumọ eyi ni pe awọn aṣaaju ilẹ Hausa ti gba Fayẹmi gẹgẹ bii ọmọ Sardauna, nidii eyi, oun ni wọn fẹẹ mu bii aṣaaju oloṣelu adugbo wọn. Bo tilẹ jẹ ko fi gbogbo ẹnu sọrọ naa, nigba ti wọn ba ti le gba a gẹgẹ bii ọmọ Sardauna, to si jẹ lati ẹnu Sultan lo ti jade, ko si ipo pataki ti wọn to Sardauna si ju aṣaaju oloṣelu fun gbogbo awọn Hausa lọ, nibi yoowu ti wọn ba si ti darukọ Sardauna, tabi ẹni yoowu ti wọn ba da orukọ rẹ mọ, ẹni ọwọ pata gbaa ni. Ọrọ yii mu ijaya ba awọn oloṣelu Guusu Naijiria, paapaa awọn ti ilẹ Yoruba nibi. Kin ni Fayẹmi ṣe fun wọn, ifẹ wo ni wọn ni si i to bẹẹ, ohun ti wọn n beere laarin ara wọn niyi.
Ko le ṣe ko ma mu ijaya dani o, nitori lọwọlọwọ bayii, Fayẹmi ni olori ẹgbẹ awọn gomina, eyi ni pe ẹnu rẹ tolẹ gan-an laarin awọn gomina orilẹ-ede yii pata. Bẹẹ awọn gomina yii ti n fa a tipẹ pe bi aarẹ kan ba gbejọba silẹ, awọn gomina to ti lo ipo wọn tan lo yẹ ko maa bọ sipo aarẹ. Eyi ni pe awọn gomina wa lẹyin Fayẹmi ju ẹlomi-in ti ki i ṣe gomina lọ. Bakan naa ni El-Rufai ti i ṣe gomina Kaduna yii ko fi bo pe oun ko fẹran Aṣiwaju Tinubu, o ti sọ ọ ni gbangba, o si sọ ọ ni kọrọ, pe oun ko fẹran rẹ rara. O sọ bẹẹ nigba ti Aregbẹṣọla n ṣe ọjọọbi rẹ, o ni oun fẹran an rẹ daadaa, ṣugbọn oun ko fẹran Tinubu ọga ẹ, nitori ki i ṣe eeyan toun fara mọ tiẹ. Ko too di ba yii naa, El-Rufai yii ti wa si Eko, to ni oun fẹẹ kọ awọn ara Eko ati awọn gomina ibẹ ni ọna ti wọn fi le gba ara wọn silẹ lọwọ Baba-isalẹ oloṣelu to n fi wọn jẹun.
Bẹẹ El-Rufai ko yee tẹnu mọ ọn pe lati Guusu Naijiria ni aarẹ tuntun yoo ti wa ni ọdun 2023, o ni oun ko ni i tẹle ondupo aarẹ yoowu lati Ariwa lọdun naa, ẹnikẹni to ba si jade, oun yoo gbegi dina fun un ni. O ni aarẹ gbọdọ wa lati Guusu ṣaa ni. Bi aarẹ yoo ba wa lati Guusu, ti El-Rufai n sọ bẹẹ, to si ni oun ko fẹran Tinubu, to si n tẹle Fayẹmi lẹyin kiri gbogbo ilẹ Hausa, ko si tabi-ṣugbọn nibẹ ju pe oun ni wọn fẹ lọ. Awọn Tinubu naa ti ri eleyii, nitori bẹẹ lawọn naa ṣe jade lọsẹ to kọja, bo tilẹ jẹ pe wọn ti n sa pamọ tẹlẹ, ti Tinub si n sọ pe ko ti i ya ti oun yoo du ipo aarẹ. Lọsẹ to kọja ni wọn ṣe ifilọlẹ igbimọ ipolongo eto idupo Tinubu, orukọ ti wọn si pe e ni SWAGA (South West Agenda) Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye lati Ekiti ni wọn fi ṣe olori igbimọ ipolongo naa. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti de ile Olubadan, ti wọn si de ọdọ Alaafin.
Eto ti wọn ṣe naa nidii, idi meji pataki lo si ni pẹlu. Akọkọ ni pe Dayọ Adeyẹye ti wọn mu lati ṣe olori ipolongo yii, ọmọ ipinlẹ Ekiti ni, oloṣelu nla lati Ekiti ni, ọjọ rẹ si ti pẹ gan-an ni agbegbe naa. Ninu AD lo wa tẹlẹ, nigba to ya lo lọ sinu PDP, ibẹ ni Fayẹmi si ti lọọ fa a jade lasiko idibo to kọja pe ko waa lọ sile-igbimọ aṣofin, ko too di Sẹnetọ. Ṣugbọn ile-ẹjọ gba ipo sẹnetọ kuro lọwọ rẹ, inu ọkunrin naa ko si dun, nitori o ro pe Fayẹmi ko ba oun rin si ọrọ naa bo ti tọ, ati pe o ṣee ṣe ko jẹ Fayẹmi kan fi ipo naa tan oun jẹ lasan ni. Loootọ inu APC naa ni wọn jọ wa, ṣugbọn ọrẹ aja pẹlu ẹkun ni wọn jọ n ṣe. Ohun to jẹ ki wọn mu Adeyẹye lati ṣe olori eto yii niyi, nitori wọn mọ pe oun nikan lo le kapa Fayẹmi ni Ekiti, ti yoo si ri ọmọ APC pupọ ko si ẹyin Tinubu nigba ti ọrọ naa ba de oju rẹ gan-an.
Lọna keji, idi ti wọn fi sare lọ si ile awọn ọba, ti wọn si pe ipolongo Tinubu ni ti Yoruba ni ki wọn le sọ pe eyi ti Fayẹmi ati awọn eeyan rẹ fẹẹ ṣe ki i ṣe ti Yoruba, pe ti awọn Hausa ni, nitori awọn Hausa lo fa a kalẹ, idi ti wọn si fi sare lọ sile Alaafin ati Olubadan niyi. Eyi lo fihan pe ija orogun ti bẹrẹ laarin awọn mejeeji, Tinubu ati ọmọọṣẹ rẹ, Fayẹmi. Awọn eeyan Fayẹmi naa ko gbe ẹnu wọn fun alagbafọ, tabi ki wọn dawọ duro. Lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti ri i pe awọn eeyan Tinubu rin iru irin yii, paapaa to jẹ Adeyẹye lo ṣaaju wọn, niṣe ni awọn naa jade lorukọ ẹgbẹ APC ipinlẹ Ekiti, ti wọn si kede pe ki Fayẹmi ma duro mọ o, ko jade bayii bayii, ko waa du ipo aarẹ lọdun 2023. Niṣe ni alaga ẹgbẹ naa, Paul Ọmọtọṣọ, jade pẹlu owe pipa si Tinubu ati awọn eeyan rẹ. O ni lasiko yii, Ekiti ko ni i ṣe ẹru ẹnikẹni mọ nidii oṣelu nilẹ Yoruba, nitori ẹ lawọn ṣe fẹẹ fa ẹni to kun oju oṣuwọn kalẹ lati du ipo aarẹ.
Ọkunrin alaga APC yii ni ko si ẹlomi-in to tun kun oju oṣuwọn lati du ipo aarẹ Naijiria lati ilẹ Yoruba ni 2023 ju Kayọde Fayẹmi lọ. O ni awọn ti n bẹ ẹ, ko si si ohun to le ṣe ju ko gbọ ẹbẹ awọn, ko si gba lati ṣe aarẹ Naijiria lọ. Ẹni to ba mọ bi ọrọ oṣelu Naijiria ti ri, yoo ti mọ pe ko si bi alaga ẹgbẹ APC Ekiti yoo ti sọrọ ti ko ni i lọwọ gomina naa ninu, ohun ti a ba fọn fun fere ni fere yoo fọn jade ni. Bi ọrọ ti wa yii, ko si ẹni to le sọ ọ mọ, Tinubu yoo du ipo aarẹ lorukọ APC, Fayẹmi naa yoo si du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ yii kan naa. Eyi ni pe nigba ti wọn yoo ba dibo abẹle lati mọ ẹni ti APC yoo fa kalẹ gan-an, lati ilẹ Yoruba nibi yii, Tinubu ati Fayẹmi ni yoo koju ara wọn. Ọrọ naa yoo le diẹ, nitori awọn ọmode yoo wa lẹyin Fayẹmi, awọn agbaagba ẹgbẹ yoo si wa lẹyin Tinubu, ẹni yoowu to ba si ni ibo awọn APC lati ilẹ Hausa ni yoo bori laarin wọn.
Bo tilẹ jẹ pe APC paapaa ko ti i sọ pe awọn fẹẹ fun awọn ara Guusu, boya ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo ni ipo naa, ko jẹ tiwọn nikan lọdun 2023 yii, awọn eeyan gbagbọ pe ibẹ ni ọrọ naa yoo pada ja si. Ati pe bi ko ba pada ja sibẹ naa, ki awọn Hausa naa jade, ki awọn Ibo naa jade, bi ko ba ti si ibara-ẹni-ja laarin awọn ọmọ Yoruba oloṣelu APC, awọn ni kinni naa yoo ja si lọwọ. Amọ bi nnkan ti n lọ bayii, nibi ti Tinubu ati Fayemi ba ba ọrọ naa de, gbogbo aye ni yoo foju ri i. Awọn mejeeji ni wọn sun mọ Buhari, bi Tinubu ti sun mọ ọn, bẹẹ naa ni Fayẹmi sun mọ ọn, ọpọ ohun ni Fayẹmi si n ṣe to n sọ pe Buhari lo faṣẹ si i ki oun too ṣe e, bẹẹ ni ọpọ awọn gomina Yoruba ninu APC wa lẹyin rẹ, ati awọn ti wọn ti fipo naa silẹ paapaa. Ṣugbọn ohun ti agba fi n jẹkọ lọrọ Tinubu, abẹ ewe lo wa, igbẹyin ni alayo yoo si ta. Bi ikun lo loko, bi pakute ni, asiko naa fẹrẹ to o.