Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nitori ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun, ajọ to n ri si idagbasoke awọn gareeji nipinlẹ Ogun (Ogun State Parks and Garages Development Agency (PAGADA), ti bẹrẹ eto lati gbogun ti awọn ti wọn n ta paraga lawọn gareeji, pẹlu awọn ọmọọta ti wọn n mugbo nibẹ, ti wọn si n jale.
Koda, wọn ti fọrọ naa to ajọ to n ri si lilo oogun oloro (NDLEA) leti, bẹẹ naa si ni awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ alaabo loju popo pẹlu ti ni ajọsọ lori igbesẹ yii lati palẹ awọn tọwọ wọn ko ba mọ ni gareeji mọ.
Alaga PAGADA nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Abeeb Ajayi, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ to kọja yii niluu Abẹokuta.
Ọkunrin naa sọ pe yatọ si tawọn eeyan ti ko ṣiṣẹ ọmọluabi ni gareeji tawọn fẹẹ ko kuro nibẹ yii, o ni aṣẹ tun ti wa pe kawọn onitirela ti wọn n daamu ọna marosẹ Eko s’Ibadan ṣọra wọn gidi, paapapa awọn ti wọn maa n paaki sẹba ọna l’Ogere.
O fi kun alaye naa pe gbogbo ohun to n fa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ lawọn ọna bii Mowe, Ibafo ati Ogere ni ajọ yii fẹẹ mojuto bayii, idi si niyẹn ti wọn ṣe fidi kootu alagbfeeka kan kalẹ si Ogere, eyi to jẹ ti FRSC. Awọn awakọ to n tapa sofin irinna ni wọn yoo maa mu, ti wọn yoo si maa gba idajo oju ẹsẹ gẹgẹ bi Ajayi ṣe wi.
Bakan naa lo ni ijọba ti paṣẹ pe akọsilẹ orukọ awọn to n ṣiṣẹ ni gareeji gbọdọ wa, yala awakọ ni tabi ọmọ ẹyin ọkọ, yatọ si bo ṣe jẹ awọn ọmọ ole atawọn ọmọọta kun awọn gareeji gbogbo.
Gbogbo igbesẹ yii ki i ṣe lati gba iṣẹ lọwọ awọn yuniọn tabi lati ba wọn pin iṣẹ wọn ṣe, Alaga PAGADA sọ pe ohun tijọba Dapọ Abiọdun ran awọn ni lati le awọn eeyan ti iṣẹ wọn ko ran ẹnikẹni lọwọ kuro ni gareeji, ki sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ dinku patapata, ko si ma si alọnilọwọgba atawọn oniparaga ni gareeji kankan mọ nipinlẹ yii.