Monisọla Saka
Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti sọrọ pẹlu iyangan lasiko to gbalejo awọn aṣaaju ọmọ Yoruba kan pe ilẹ Naijiria n ku lọ, inu ipayinkeke lo si wa, lasiko toun depo lọdun to kọja, amọ ti ijọba oun ti fopin si gbogbo wahala naa.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Aarẹ sọrọ yii lasiko tawọn aṣoju Yoruba Leaders of Thought, ba a lalejo nile ijọba, l’Abuja.
O ni eto iṣejọba gbọdọ jẹ eyi ti yoo mu ayipada wa, o si gbọdọ yanju nnkan tawọn eeyan nilo ni pataki. O ni lati bii ọdun kan toun ti n tukọ orilẹ-ede yii, eto iṣejọba oun n dabira pẹlu bi awọn adojukọ ṣe n yọju.
“O le koko, nitori ó wá pẹlu adojukọ, bẹẹ lo si n ni abayọri bakan naa. A gba iṣakoso, a si fopin si wahala to ba ilu. Mo le fi gbogbo ẹnu sọ ọ bayii pe ko si idaamu kankan mọ fun ilẹ Naijiria, bẹẹ ni idaamu naa ko ni i gbẹmi rẹ, ṣugbọn ti yoo maa tibi igbega bọ si igbega. Ileri ti mo ṣe fun gbogbo yin niyẹn, iṣẹ tẹyin naa si gbe le mi lọwọ ni.
“A n gbiyanju lati wẹ okun yii ja ni, ki i ṣe ohun to rọrun rara, amọ a o wẹ ẹ ja, mo fi n da yin loju. Mo n mọ-ọn-mọ ṣe pẹlẹpẹlẹ. Gbogbo akoko iṣoro yii ti dopin fun Naijiria, a maa moke dandan ni.
Mo dupẹ pupọ lọwọ awọn ikọ ti wọn ti n ṣiṣẹ takuntakun. Gbogbo ohun ti mo le fi ṣeleri ni pe gbogbo ohun to ba gba la maa ṣe. A ti pinnu, a o si ṣiṣẹ ki awọn ọmọ Naijiria le mọ ipa ijọba rere lara.
“Igbelarugẹ n lọ fun eto ilera. Bẹẹ la n ṣe ọna tuntun ati atunṣe awọn mi-in. Eto ẹkọ ti a n ṣeto idagbasoke fun naa ko gbẹyin. Mo n sọ fun yin nisinyii pe kẹ ẹ wo nnkan to n lọ nipinlẹ ẹnikọọkan yin. Ẹ wo nnkan tawọn gomina ipinlẹ yin n ṣe. Ẹ sọ fun wọn ki wọn mu ojuṣe wọn ni pataki, ki wọn si jẹ ki awọn eeyan wọn jẹ afojusun eto idagbasoke wọn.
Ti ajọṣepọ ba ti wa laarin wa, mo le fi da yin loju pe ilẹ Naijiria yoo jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede to daa ju tẹ ẹ le ri lorilẹ aye”.
Aarẹ Tinubu to koro oju si ọrọ iṣejọba nipele ijọba ibilẹ lorilẹ-ede yii pe fun eto ijọba ibilẹ ti yoo tẹpẹlẹ mọ idagbasoke agbegbe, ti yoo si ba awọn araalu ṣe gẹgẹ bo ṣe yẹ.
Bakan naa lo pe fun ijọba to n ṣiṣẹ loju mejeeji ni gbogbo ipele iṣejọba atawọn ileeṣẹ ijọba jake-jado orilẹ-ede yii. O ni ijọba to n ṣe ẹtọ ati itọju ori-o-ju-ori faraalu ni toun.
“Eto ijọba ibilẹ n ku lọ. Ohun temi ko ni i fara mọ ni ki ijọba ibilẹ waa ko gbogbo ojuṣe wọn le ijọba apapọ lọrun. Iwa ọdaran leleyii ninu iṣejọba to n ṣamulo ipele mẹtẹẹta.
“Ijọba to n lo Aarẹ la n ṣe. A ni ipele ti ipinlẹ ati ti ijọba apapọ. Meji ni, awọn ipinlẹ gbọdọ ṣe gbogbo nnkan to wa nikaawọ wọn lori iṣejọba wọn. Ki i ṣe ọrọ dandawii. Nnkan ti a gbọdọ se niyẹn nipa wiwo ọrọ owo to n wọle si apo ipinlẹ kọọkan latoke, ki a si ri i daju pe a o yẹsẹ lori ijọba to n lo Aarẹ. Gbogbo awọn nnkan ti mo n fẹ ki ẹ maa reti lati ọdọ mi niyẹn, ki i ṣe ọrọ pe ki ni yoo ṣẹlẹ lasiko ibo to n bọ”.
Tinubu to dupẹ lọwọ awọn ti wọn ba a lalejo rọ wọn pe ki wọn tubọ maa ṣatilẹyin fun Naijiria, ki wọn si nigbagbọ kikun ninu rẹ. Ati pe, ijọba oun ko ni i ja wọn kulẹ’’.
Bayọ Aina, to sọrọ lorukọ Olori ẹgbẹ Yoruba Leaders of Thought, Ọmọọba Tajudeen Oluyọle Olusi, gboṣuba kare fun Aarẹ lori bo ṣe mu iṣẹ ṣiṣe kaakiri awọn ẹka ati ileeṣẹ ijọba bii ileeṣẹ eto ilera, eto irinna ojupopo ati ofurufu, to fi mọ eto ẹkọ ni pataki, ati gbogbo akitiyan lati ṣeto ijọba to mọyan lori lorilẹ-ede Naijiria.