Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Okobo awọn ọre meji yii, Ganiyu Lawa ati Ademọla Waheed, ko bimọ sitosi nidii iṣẹ okoowo ole ti wọn yan laayo o, ipinlẹ Eko lọhun-un ni wọn ti lọọ ji mọto onimọto gbe, ni wọn ba gbe e wa si Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lati waa ta a. Asiko naa ni wọn ko sọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Kwara to n gbogun ti awọn to n ji ọkọ gbe, ni wọn ba mu wọn ṣinkun. Wọn ṣi wa lakata awọn agbofinro ti wọn n ṣẹju pako bii maaluu to rọbẹ titi di ba a ṣe n sọ yii.
Nigba to n fidi iwa ọdaran naa mulẹ fun akọroyin wa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, sọ pe Opopona Sáńgò, niluu Ilọrin, lọwọ ti tẹ awọn afurasi mejeeji yii lasiko tawọn ọlọpaa n yẹ awọn mọto wo fínnífínní lagbegbe. Wọn ri nọmba foonu to jẹ ti ẹni to ni mọto naa, iyẹn Ọgbẹni Ajibade Abel, to n gbe ni agbegbe Badagry, niluu Eko. Awọn agbofinro pe ọkunrin naa, o si fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn ji mọto oun gbe, toun si ti lọọ fẹjọ sun ni aagọ ọlọpaa to wa ni agbegbe wọn.
Adetoun fi kun un pe nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, wọn ṣalaye pe ilu Eko, ni awọn ti ra ọkọ naa ni ẹgbẹrun-un lọna irinwo Naira (400,000), pẹlu erongba pe awọn yoo ta a ni miliọnu kan Naira.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Victor Ọlaiya, gboṣuba fun awọn ọlọpaa ipinlẹ naa atawọn araalu pẹlu bi wọn ṣe fọwọsọwọpọ pẹlu awọn ọlọpaa lati maa ta wọn lolobo lori awọn ọdaran ti wọn ba kẹẹfin.
Kọmiṣanna tun waa rọ awọn eeyan naa lati maa ke sawọn agbofinro bi wọn ba ti ri awọn ajeji lagbegbe wọn.
O fi kun un pe awọn ọdaran meji ti ọwọ tẹ ọhun yoo foju bale-ẹjọ, ti wọn aa si foju wina ofin lẹyin ti iwadii ba pari.