Ẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn apaayan ni ọkunrin yii, Danladi Lawal, ẹni ogun ọdun, wa bayii nipinlẹ Niger. Iyawo ẹ, Zulai Lawal, lo lu pa lọsẹ to kọja yii, nitori ẹkọ tiyẹn po fun un ti ọkunrin yii sọ pe o dikoko.
Abule Kadaura, nijọba ibilẹ Rafi, nipinlẹ Niger, ni ọkunrin yii ati iyawo rẹ kekere naa n gbe.
Ẹkọ tọkọ ni ko po foun, ti Zulai po, ni ọkọ rẹ sọ pe ko po daadaa, ati pe koko pọ ju ninu ẹkọ ọhun.
Danladi binu pupọ nitori ẹkọ naa, o si jọ pe iyawo rẹ ko bẹ ẹ bo ṣe fẹ, nitori niṣe lọrọ di ija nla, to dohun ti Danladi bẹrẹ si i luyawo ẹ, o si lu u titi tọmọbinrin naa fi daku mọ ọn lọwọ.
Ọkọ yii funra ẹ ṣalaye fawọn akọroyin, nigba tawọn ọlọpaa foju ẹ han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Minna. O ni loootọ ni inu bi oun, toun si lu iyawo oun laluju, to bẹẹ to jẹ o daku. Danladi sọ pe oun ko mọ pe ko ni i ji pada saye lẹyin to daku naa. O loun gbe e lọ sọsibitu Jẹnẹra Wushishi, ṣugbọn wọn sọ foun pe o ti ku.
Ko pẹ ti gbogbo abule fi gbọ pe Zulai ti ku latari lilu tọkọ rẹ lu u, kia lawọn ọlọpaa si ti waa gbe Danladi lọ si teṣan.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Niger, DSP Wasiu Abiọdun, sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn Danladi yoo de kootu laipẹ rara.