Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ọsẹ mẹta ti gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ku, ọkan ninu awọn kọmiṣanna to ṣiṣẹ ninu ijọba rẹ, Ọnarebu Fatai Abimbọla tawọn eeyan mọ si Abọgun, ti dagbere faye.
Nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja ni wọn lo ku sinu ijamba ọkọ lọna Eko s’Ibadan.
Ọnarebu Abọ̀gún lo ti kọkọ ṣe kọmiṣanna fawọn nnkan alumọọni ijọba ipinlẹ Ọyọ lasiko iṣejọba Oloogbe Ajimọbi.
Lẹyin naa lo tun ṣe oludamọran fun gomina yii kan naa lori ọrọ gbogbo to ba ni i ṣe pẹlu ohun amuṣọrọ ijọba nigba ti Ajimọbi ṣatunto ileeṣẹ ijọba atawọn eeyan to yan sipo lọlọkan-o-jọkan.
Ipo oludamọran yii lo wa to fi dupo gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Party, APC, ṣugbọ̣n ti Oloye Adebayọ Adelabu la oun ati gbogbo awọn to ba a dupo naa mọlẹ ninu idibo abẹle ẹgbẹ wọn, ki Ẹnjinia Ṣeyi Makinde to dupo lorukọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP too fagba han Adelabu paapaa ninu idibo gbogbogbo to waye lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹta, ọdun 2019.
Ijamba ọkọ to ṣẹlẹ si Ọnarebu Abọgun lọna Eko s’Ibadan nirọlẹ ọjọ Jimọ to kọja yii lo fopin si gbognbo ilakaka ẹ nidii oṣelu, ati gbogbo làálàá ẹ lorilẹ aye.
Oludamọran fun ijọba Ajimọbi lori ọrọ to ni i ṣe pẹlu awọn akẹkọọ, Ọgbẹni Afeez Mobọlaji, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Rẹpẹtẹ, lo tufọ iku baba yii lori ikanni ibanidọrẹẹ (Fesibuuku) rẹ lalẹ Jimọ to kọja.
Lẹyin naa l’Ọgbẹni Wale Sadeeq ti oun jẹ oludamọran fun gomina tẹlẹ naa lori eto iroyin fidi iroyin ọhun mulẹ lori ẹrọ ayelujara bakan naa.