Ọlawale Ajao, Ibadan
Ẹkun lawọn ti ko le mu iṣẹlẹ naa mọra bu si nigba ti wọn ri oku ọkunrin kan, Taoreed Oluṣọla, nilẹẹlẹ lẹyin ti awọn adigunjale yinbọn pa a ti wọn si ja a lole owo to ṣẹṣẹ gba ni banki.
Ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan ana, Mọnde, ọjọ Aje niṣẹlẹ ọhun waye nitosi sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Agodi n’Ibadan.
Ileefowopamọ kan ni Bodija la gbọ pe ọkunrin to n gun ọkada lọ naa ti gbowo ki awọn adigunjale meji ọhun ti awọn naa wa lori ọkada too tẹ le e debi ti wọn pa a si ti wọn si ja owo ọwọ ẹ gba.
Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe sọ, bi Taoreed ṣe de itosi Sẹkiteriati lo ya bara sọna ileejọba ipinlẹ Ọyọ (Government House) lAgodi, nigba lo fura pe oun lawọn meji to wa lori ọkada to n bọ lẹyin oun n tẹ le.
Nigba naa lawọn ẹruuku yinbọn lu u, ti wọn si gbe baagi owo ọwọ ẹ lọ nibi to ti n pọkaka iku lọwọ, ko too pada gbẹmi-in mi.
Iwe akọsilẹ owo ti oloogbe yii gba, eyi ti wọn ba lara ẹ lẹyin to ku tan fi han pe ẹgbẹrun lọna ojilenirinwo Naira o le mẹfa (N446,000) lowo to ṣẹṣẹ gba nileefowopamọ.
Awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ lẹka eto imọtoto ayika ni wọn gbe oku ẹ lọ si UCH, iyẹn ileewosan ijọba apapọ, to wa nitosi Agodi n’Ibadan.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fakọroyin wa.O ni ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti paṣẹ pe ki awọn agbofinro bẹrẹ iwadii lati ri ọdaju eeyan to huwa ika ọhun mu laipẹ jọjọ.