Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ ti sọ pe ki wọn lọọ fi ọdọmọkunrin kan, Matthew Tersen, pamọ sọgba ẹwọn titi dinu oṣu keji ti igbẹjọ yoo tun waye lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.
Matthew ni agbefọba, Inṣpẹkitọ James Ọbaletan, sọ fun kootu pe o huwa naa laago kan ọsan ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kejila, ọdun to kọja.
Ṣe lo lọ sile ọga rẹ, Abọlaji Bukọla, lagbegbe Oluṣanu Hospital, ni Garage Ọlọdẹ, nijọba ibilẹ Guusu Ifẹ, to si ji miliọnu kan aabọ naira (#1.5m).
Ọbaletan sọ siwaju pe iwa olujẹjọ nijiya labẹ ofin irinwo o din mẹwaa (390) ati okoolenirinwo o din mẹjọ (412) ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Bi wọn ṣe ka ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an si i leti lo ti sọ pe oun jẹbi.
Lẹyin naa ni Adajọ A. A. Adebayọ paṣẹ pe ki wọn maa gbe e lọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ lati le jẹ ẹkọ fun awọn ọdọ to jẹ pe wọn ko ṣetan lati ṣiṣẹ ki wọn too ri owo.
O waa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun yii.