Awọn ọmọ mi kan n yọ mi lẹnu, bẹẹ naa ni awọn ọrẹ mi kan ti a jọ jẹ ẹgbẹ, ati awọn mi-in ti wọn jẹ ẹgbọn fun wa. Gbogbo wọn ni wọn n daamu mi lori ọrọ to n lọ nilẹ Yoruba bayii. Ọrọ naa ni pe ‘Dandan Ni Ki Yoruba Ya Kuro Lara Naijiria!’ Ohun ti wọn ṣe n daamu mi ni pe wọn ni mi o da si i. Wọn ni n ko sọ si ọrọ naa, ati pe agbenimáfọhùn, a ko mọ ti ẹni to n ṣe. Wọn ni ṣe emi ko fara mọ ọn ki Yoruba kuro ni ara Naijiria ni, tabi n ko ri iya to n jẹ wa ni Naijiria yii. Nigba ti mo bẹrẹ ọrọ lati ṣalaye ohun ti awọn ọdọ le ṣe, ati bo ṣe jẹ ọwọ wọn ni ọjọọla Yoruba ati ti orilẹ-ede yii wa, ohun ti awọn kan tun tẹnu mọ fun mi ni pe Yoruba ko si lara Naijiria sẹẹ, pe gbogbo ọna ti a ba le tọ lati ri i pe Yoruba kuro lara Naijiria ni ka tọ, nitori ohun to n ṣẹlẹ yii to gẹẹ, awọn eeyan kan wa ti Yoruba ko le ba ṣe, afi ki kaluku ṣe tiẹ lọtọ.
Adaba n pogede, o ṣe bi ẹyẹle ko gbọ, ẹyẹle gbọ, titiiri lo n tiiri ni. Ṣe ma a sọ pe n ko gbọ ariwo to n lọ ni, tabi mo fẹẹ ni n ko mọ awọn ti wọn n gbe oriṣiiriṣii ẹgbẹ silẹ pe afi ki Yoruba ya lara Naijiria, tabi mo fẹẹ sọ pe wọn ko waa fi ọrọ naa to mi leti ni. Wọn waa fi to mi leti, wọn si sọ fun mi daadaa, bẹẹ ni mo si gbọ awuyewuye awọn mi-in ti n ko mọ, ohun ti wọn si n sọ ni pe ki Yoruba maa lọ lo dara. Ti mo ba ri ọgbọn rẹ da, tabi ti agbara nla kan ba wa lọwọ mi, Yoruba ko ni i sun oorun ọjọ kan si i mọ ni orilẹ-ede Naijiria, Yoruba yoo ya, awọn ti wọn ba si fẹẹ ṣe Naijiria yoo maa ṣe Naijiria wọn lọ. Ṣugbọn o, ọrọ yii ni awọn “ṣugbọn” kan ninu, afi ki eeyan si mọ awọn “ṣugbọn” to wa ninu ọro naa ko too bẹrẹ ija, bi bẹe kọ, tọhun yoo jẹbi, yoo si fi ọpọ ẹmi awọn ti wọn n jẹ Yoruba ṣofo. O da mi loju pe ki i ṣe ohun ti Yoruba fẹ niyẹn.
Bi ọpọlọpọ yin ti fẹ ki Yoruba ya kuro lara Naijiria, bẹẹ lemi naa fẹ. Mo fẹ ka bọ loko ẹru awọn amunisin yii, ki a bọ ninu ajaga ti awọn oloṣelu wa to n ṣiṣẹ fun Fulani ki bọ wa lọrun, nitori ọrọ naa ti di iwọsi, o si mu ẹgbin pupọ dani. Ṣe ohun ti wọn n ṣe kiri ilu yii daa ni! Tabi ti Buhari to yiju si ẹgbẹ kan ti awọn ẹya tirẹ n jẹ awa to ku niya leeyan yoo ro ti ibinu ko ni i ru bo tọhun loju! Iru iyanjẹ ati ifiyajẹni to n lọ nilẹ yii, ko si ibi ti wọn ti n gba iru ẹ; ko si si ibi ti iru ẹ ko ni i di ija rẹpẹtẹ to ba ya. Ṣugbọn ni temi, ẹjọ la a kọ ka too kọ ija, awọn ‘’ṣugbọn’’ ti mo ni o wa ninu ọrọ yii, afi ka yọ wọn kuro na, bi a ba ti yọ wọn kuro, ibi yoowu ti a ba fẹe lọ, ati igba yoowu ti a ba fẹẹ lọ, ko le si wahala fun wa. Iyatọ to wa laarin emi atawọn ti wọn n pariwo pe ki Yoruba maa lọ kuro lara Naijiria lẹsẹkẹsẹ niyẹn. Bawo la ṣe fẹẹ lọ? Nibo la fẹẹ lọ? Awọn ibeere temi niyẹn.
Ni Naijiria ti a wa yii, ọna meji pere ni ẹya kan fi le kuro lara awọn to ku, ti wọn yoo ni awọn ko ṣe mọ, awọn fẹẹ maa ṣe tawọn lọtọ. Ọna akọkọ ni nipasẹ ofin. Idi eyi ni pe ajọṣe awọn ẹya to wa ni Naijiria yii ko deede bẹrẹ, ofin la fi bẹrẹ ẹ. Oriṣiiriṣii ipade apero lori ofin ti wọn yoo maa fi ṣejọba ni Naijiria lawọn baba wa ṣe ki ọrọ too de ibi to de duro yii, lara awọn ofin ti wọn si ṣe nigba kan ni pe ko si ẹya kan to le deede kuro lara Naijiria, lai jẹ pe awọn ẹya to ku fọwọ si i. Nidii eyi, bi Yoruba ba fẹẹ lọ, afi ki a jokoo si ile-igbimọ aṣofin, laarin awọn aṣofin wa wọnyi, nibi ti awọn APC ati PDP ti n jọba, ka si sọ pe a ko ṣe Naijiria mọ. Awọn aṣofin ni yoo waa yi ofin pada, ti wọn aa sọ pe ẹya yoowu ti ajọṣepọ Naijiria ko ba tẹ lọrun mọ le maa lọ to ba fẹẹ lọ. Nidii eyi, ko si ẹni kan ti yoo da wa duro, tabi ti yoo di wa lọwọ mu, ti a ba ti ni a fẹẹ maa lọ.
Ni ọna keji ẹwẹ, ti a ko ba fẹẹ gba ibi ti awọn olofin de yii, ti a ba ni a ko fẹ ofin, ọrọ naa ti su wa, a ko si fẹ ajokoo-sọ kankan, a fẹẹ maa lọ ni. Eyi tumọ si pe a ti mura lati jagun ree, nitori ija la fẹẹ fi lọ yẹn. Ija la fẹẹ fi lọ nitori awọn to ku ko fọwọ si i pe ka lọ, ijọba apapọ si le lo awọn ọlọpaa ati awọn ọmọ ogun wọn lati da wa duro. Bi wọn ba ko awọn ọlọpaa tabi ṣọja jade, ti a ba ni a ko gba, ọrọ naa yoo di ogun ni, wọn yoo si ba wa ja titi ti a oo fi ṣẹgun wọn, tabi ki wọn ṣẹgun wa. Iru ohun to ṣẹlẹ ni ọdun 1967 si 1970 niyẹn, nigba ti awọn ọmọ Ibo ni awọn fẹẹ maa lọ, awọn fẹẹ kuro lara Naijiria, awọn ko jẹ Naijiria mọ, Biafra lorukọ awọn tuntun. Awọn to ku: Hausa, Yoruba, Ijọ ati lara awọn ọmọ Ibo mi-in paapaa funra wọn ni awọn o gba, ko si ẹya kan ti aa kuro lara Naijiria; Naijiria ni gbogbo wa gbọdọ jọ maa jẹ. N lọrọ ba dogun.
Lapapọ, awọn bii miliọnu meji ọmọ Ibo ni wọn ku, bi wọn si ṣe ku naa to, wọn ko ri orilẹ-ede Biafra ti wọn fẹẹ gba yii gba, wọn kan fi ẹmi awọn eeyan ṣofo lasan ni. Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Ibo mura ogun, awọn jagunjagun wọn ti wọn jẹ ṣọja ni Naijiria tẹlẹ para pọ lati ri i pe awọn ṣẹgun, ti wọn si mura gan-an si ija naa, titi ti wọn fi fọdun mẹta ja a, sibẹ, awọn ọmọ ogun Naijiria pọ ju wọn, wọn lowo lọwọ ju wọn, wọn ni ọmọ ogun ju wọn, wọn si lo gbogbo ẹ lati ri i pe wọn ko jẹ ki wọn lọ. Nibi yii ni eeyan yoo ti mọ bi ọrọ ẹya kan to ba fẹẹ lọ lorilẹ-ede yii ni tipatipa ti le yọri si, ati ohun to le ṣẹlẹ si wọn. Bi ki i baa ṣe pe ẹya to ba fẹẹ kuro ni Naijiria ni ọmọ ogun to to, to si ni owo rẹpẹtẹ ati irinṣẹ ijagun to pọ, iṣoro ni yoo koju rẹ, nitori wọn aa kan sọ gbogbo agbegbe wọn di oju ogun ni, ti wọn aa maa pa tọmọde tagba, tọkunrin tobinrin.
Mo waa fẹ ki awa naa jokoo ka wo o, ka ronu wa lori ọna mejeeji ti mo la kalẹ pe a fi le kuro loriẹ-ede yii. Bẹẹ ki i ṣe emi ni mo la ọna mejeeji kalẹ, bi ofin ti wi ni, bi ọrọ si ti ri ni. Njẹ awọn Yoruba ni awọn aṣofin ti wọn le ja fun wa, awọn aṣofin ti wọn aa duro niwaju ile-igbimọ apapọ, ti wọn aa ni a ko ṣe Naijiria mọ, ti ẹnu wọn yoo ko, ti wọn aa fi ohun kan sọrọ bẹẹ laarin awọn ẹlẹgbẹ wọn to ku. Ṣe awọn aṣofin APC ti wọn jẹ ọmọ Yoruba ni wọn aa ṣe bẹẹ fun wa ni tabi awọn ti PDP! Ṣe awọn oloṣelu ilẹ Yoruba yii yoo dide lọjọ kan ṣaa, ti wọn aa lọ sile-igbimọ aṣofin pe Yoruba fẹẹ lọ! Bẹẹ awọn nikan ni wọn le lọ sibẹ ti ẹni kan yoo gbohun wọn, nitori awọn ni aṣoju Yoruba nibẹ, bi ẹlomiran lọ sibẹ to n pariwo, aja lasan lo n gbo ni o. Awa naa mọ pe awọn aṣofin wa yii o ni i lọ. Bi wọn si debẹ, wọn o ni wi nnkan kan.
Tabi ti ọrọ ba waa yi biri, to dogun, ti Yoruba ba ni awọn fẹẹ lọ lojiji, awọn jagunjagun wo la ni nilẹ yii o! Awọn jagunjagun wo la ni ti wọn jẹ Yoruba ti wọn le ṣaaju ogun lati ko Yoruba kuro lara Naijiria! Nibo la ni irinṣẹ ijagun wa si, ṣe ibọn la ni to jẹ tiwa ni abi ọta ibon, maṣingan-an-nu la ni ni abi ẹronpileeni adigbolulja! Bẹe bi Yoruba ba fẹẹ fi ija kuro ni Naijiria, afi ka ni gbogbo eleyii, ka le koju awọn alatako wa nigba ti wọn ba ni ka ma lọ. Ninu yin, ẹyin naa aa ri i pe eleyii ko ṣee ṣe lasiko ti a wa yii. Ki eleyii too ṣee ṣe, iṣẹ wa lọwọ Yoruba lati ṣe. Bi a ko ba ri iṣẹ eyi ṣe yanju, ẹni to ba n dabaa pe Yoruba fẹẹ kuro ni Naijiria n tan awọn eeyan jẹ lasan ni, tabi ko jẹ o kan fẹẹ maa fi ọrọ naa ko owo jọ lati ọdọ awọn kan. Ṣugbọn iyẹn ko sọ pe kinni naa o ṣee ṣe to ba ya: eto ati ipalẹmọ gidi ni.
Nibi to si ti kan awọn ọdọ wa niyi, awọn yii ni wọn yoo gba wa, awọn ọdọ ti a ni ni yoo tun ilẹ Yoruba to. Bi Naijiria ba ṣee tun to, deede; ṣugbọn awọn ni wọn le tun Yoruba to, ti wọn ba tẹle awọn ọna ti n oo la kalẹ fun wọn, tabi eyi ti awọn ti wọn ba tun ju iru awa lọ – ni ọgbọn, imọ ati ọjọ ori – ba la kalẹ. Awọn ọna ti mo fẹẹ ṣalaye ree o, ki wọn too fi ọrọ pe ka kuro ni Naijiria dandan fa mi pada diẹ, ṣugbọn a oo maa ba ọrọ wa bọ lọsẹ to n bọ. Ẹ ṣaa jẹ ka ni suuru, ẹpọn agbo n mi ni, ko ni i ja, Ọlorun yoo ṣe ọna abayọ fun wa.