Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lẹyin iku olori ileegbimọ aṣofin Ekiti tẹlẹ, Ọnarebu Funminiyi Afuyẹ, awọn aṣofin naa ti yan Ọnarebu Gboyega Aribisọgan gẹgẹ bii olori tuntun ti yoo maa dari ile wọn. Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii ni eto ọhun waye.
Aribisọgan to jẹ ọmọ bibi ilu Ijẹsa-Iṣu Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, lo n ṣoju ẹkun kin-in-ni nijọba ibilẹ Ikọle, nileegbimọ aṣofin naa lati ọdun 2015 si ọdun 2019. Bakan naa lo tun pada wọle lẹẹkeji lọdun 2019 titi di asiko yii.
Aribisọgan ni ibo mẹẹẹdogun, eyi to fi gbẹyẹ lọwọ ojugba rẹ, Olubunmi Adelugba, to wa lati ẹkun ijọba ibilẹ Emure.
Lakooko ijoko ile naa to waye ni gbọngan ile aṣofin naa ni Ọnarebu Tajudeen Akingbolu to wa lati ẹkun kin-in-ni ijọba ibilẹ Ariwa Ekiti dabaa Aribisọgan, nigba ti Ọnarebu Adegoke Ọlajide to n ṣoju ẹkun ijọba ibilẹ Ẹfọn, gbe e lẹyin. Bakan naa ni Ọnarebu Bọde Adeoye, to n ṣoju ẹkun keji ijọba ibilẹ Iwọ Oorun ipinlẹ Ekiti dabaa Arabinrin Olubunmi Adelugba, ti Ọnarebu Ojo Matins to n ṣoju ijọba ibilẹ Ijero si gbe oun naa lẹyin.
Eyi lo fa a tawọn aṣofin naa ṣe dibo, ti Aribisọgan si ni ibo mẹẹẹdogun, leyii to fi fẹyin Arabinrin Adelugba janlẹ.
Ni kete ti akọwe ileegbimọ naa ṣe ibura fun un tan, olori ile tuntun naa dupẹ gidigidi lọwọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ fun yiyan ti wọn yan an.
O ṣeleri pe oun ko ni i ja wọn kulẹ. O fi kun un pe gbogbo iṣẹ to ba yẹ lati ṣe ti yoo gbe ogo ipinlẹ Ekiti ati ti ileegbimọ naa ga loun yoo ṣe.
Ko too di asiko ti wọn yan an bii olori yii, Aribisọgan ni ọmọ ileegbimọ to pọ ju ni ile naa.