Lẹyin ọṣẹ diẹ ti ọmọ wọn, Ifeanyi Adeleke, ku sinu odo iwẹ, ọmọkunrin olorin taka-sufee nni, David Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si Davido, ati ọrẹbinrin rẹ to bimọ fun un, Chioma, ti ṣe igbeyawo bonkẹlẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Gẹgẹ bi iweeroyin PM ṣe sọ, wọn ni awo ni wọn fọrọ igbeyawo naa to waye nile awọn obi Davido ṣe pẹlu diẹ ninu awọn mọlebi mejeeji to wa nikalẹ, bẹẹ ni wọn ko si faaye gba ẹnikẹni laaye lati ya fọto ayẹyẹ igbeyawo naa.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọkunrin olorin naa ti figba kan sọ pe ọdun to n bọ loun ati Chioma maa ṣegbeyawo, o jọ pe iku ọmọ wọn yii lo jẹ ki igbeyawo naa waye ṣaaju asiko ti wọn ti fi si tẹlẹ.
ALAROYE gbọ pe wọn ni Chioma sọ pe ko tun si ohun ti oun n duro wo nile awọn Davido, nitori ọmọ to so awọn pọ naa lo ti ku yii. A gbọ pe eyi lo mu ki Davido fa ọjọ igbeyawo naa sẹyin, lati mu inu ololufẹ rẹ yii dun, ko si fun un ni idaniloju. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ṣe e lalariwo, lati fi ọmọbinrin yii lọkan balẹ pe boya ọmọ wa tabi ko si, oun ṣi nifẹẹ rẹ lo jẹ ki eto yii waye.
A gbọ pe gbogbo nnkan idana lori Chioma lawọn mọlẹbi Adeleke san lasiko ti eto naa waye. Wọn ni Chioma paapaa ti n gbiyanju lati gbe iku ọmọ rẹ yii kuro lara, bo tilẹ jẹ pe awọn ti wọn ri i sọ pe ọmọbinrin naa ti ru gan-an.